Ikọ̀ agbésùnmọ̀mí tó ṣèkọlù sí ọgbà ẹ̀wọn Kuje ní ohun ìjà jù wálọ - Ìjọba Naijiria

Ijọba orilẹede Naijiria ti ni looto ni awọn agbesunmọmi ni ohun ija ju wọn lọ ni wọn ṣe bori ni ikọlu si ọgba ẹwọn Kuje.

Minista fun ọrọ awọn ọlọpaa, Mohammed Dingyadi lo sọ bẹẹ lẹyin ipade pẹlu Aarẹ Buhari ni Abuja.

Dingyadi ni awọn agbẹsunmọmi naa tun wa ni ọgọọrọ ti wọn si pọju awọn ẹṣọ alaabo to wa nibẹ.

O ni awọn ẹṣọ alaabo gbiyanju amọ ohun ija ti awọn agbesunmọmi naa gbe wa ko dẹrun

O kere tan ọmọ ẹgbẹ Boko Haram to le ni ọgọta ni wọn tu silẹ ninu ikọlu naa.

Ẹ̀lẹ́wọn mẹ́rin ló kú nínú ìkọlù Kuje ti mẹ́rìndínlógún si farapa- Umar

Orisirisi iroyin lo ti jade sẹyin nipa ikọlu to waye ni ọgba ẹwọn Kuje nilu Abuja.

Leyin o reyin ni atejade to kun fun iroyin ohun to ṣẹlẹ ni pato jade sita bayii.

Ileeṣe ijọba apapọ to n risi ọrọ amojuto ọgba ẹwọn Naijiria lo fi atejade naa sita.

Wọn ni ado oloro ni Boko Haram fi fọ ẹnu ọna ọgba ẹwọn naa ni Kuje.

Ati pe, Awọn osiṣẹ ọgba ẹwon mẹta lo farapa yatọ si ti osisẹ\Civil Defence kan to ku.

Umar Abubakar to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ ijọba apapọ lo buwọlu atẹjade naa lorukọ oludari wọn.

O salaye pe ẹlẹwọn 879 lo salọ lapapọ lẹyin ti wọn fi ara balẹ ka gbogbo ẹlẹwọn tan.

Ati pe, ọwọ ti tẹ ẹlẹwọn 443 papda ti wọn si ti ko wọn sinu ọgba ẹ\won Kuje.

Umar só pé ẹlẹwọn mẹrin ku nínú ikọlu naa ti merindinlogun si farapa ti wọn si ti n gba itọju.

O ni igbesẹ ti n lọ lọwọ lati sisie papo pẹlu awon ọtẹlẹmuyẹ Corrections Information Management System (CIMS) àti National Identity Management Commission (NIMC) lati wa àwọn to ku to ti salọ.

O ni gbogbo awọn oloselu to wa ninu ẹ\won naa ni ko salọ rara. Pe gbogbo wọn wa lalaafia nibẹ.

‘Abba Kyari ṣì wà ní Ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje, irọ́ ni pé ó ti sálọ’

Lẹ́yìn ìkọlù tọ wáye ni Ogba ẹwọn Kuje ni Abuja ni ọpọ iroyin ti jade lori iṣẹlẹ naa.

Agbẹnusọ fun ajọ to n mojuto ọgba ẹwọn ni Naijiria salaye fun BBC pe irọ ni pe Abba Kyari to n jẹ ẹjọ lọwọ lori ọrọ Ramoni Igbalode Hush puppi ati awọn mii naa ti salọ kuro ni ọgba ẹwọn naa.

Umar Abubakar to je agbenusọ naa sọ pe Abba Kyari ko re ibi kan o.

O ni pe Abba Kyari ko si ninu ewu kankan ati pe awọn oniṣẹ ibi naa ko sunmọ tosi ibi ti wọn fi abba Kyari si ni Kuje.

O ni ibi ti awọn ọmọlẹyin Boko Haram wa ni afojusun wọn ti wọn si ṣe ikọlu si.

Ẹlẹ́wọ̀n 600 ló sálọ kúrò ní Kuje, Boko Haram ló ṣiṣẹ́ ibi náà- Minista Bashir

Minista fun eto aabo ni Naijiria, Bashir Salihi Magashi ti sọrọ lori ikólu to waye si ọgba ẹwọn Kuje nilu Abuja.

Minista dẹbi ọrọ naa ru awọn agbesunmọmi Boko Haram

O ni pe ẹlẹwọn ọgọrun un mẹfa lo salọ kuro lọgba ẹwọn Kuje loru mọju.

O ni ṣugbọn awọn ọọdunrun ti pada wa si ọgba ẹwọn naa lẹyin ti awọn osisẹ eleto aabo ri wọn ninu igbo ti wọn fi ara pamọ si.

Magashi ati akọwe agba ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ọgba ẹwọn, Shuahib Belgore salaye fun BBC pe ọkan lara awọn osiṣẹ aabo ẹni laabo ilu, Civil Defence kan padanu ẹmi rẹ ninu ikọlu naa ni Kuje.

Won ni pe wọn sin fi ọkọ ofurufu wa awọn to ku kiri.

O ni pe merinlelọgọta ninu awọn ọniṣẹ ibi Boko Haram lo wa ninu ọgba ẹwon naa tẹlẹ.

À ń ṣèwádìí ìkọlù tí àwọn agbébọn ṣe sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje lọ́wọ́- Iléeṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n

Iléeṣẹ́ tó ń ṣàkóso ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Nàìjíríà ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé lóòótọ́ ni àwọn agbébọn wá ṣe ìkọlù sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Keje, ọdún 2022.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ náà, Umar Abubakar fi síta ní ọjọ́rú ní àwọn ológun àjọ náà pẹ̀lú àtìlẹyìn àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò mìíràn tètè kojú àwọn agbébọn ọ̀hún.

Abubakar ní àláfíà ti padà sípò ní ọgbà náà.

Ó ní àwọn yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó wáyé níbẹ̀ láìpẹ́.

Abubakar kùnà láti sọ ohunkóhun lórí wí pé bóyá àwọn ẹlẹ́wọ̀n sá kúrò nínú ẹ̀wọ̀n náà lásìkò tí àwọn agbébọn ṣe ìkọlù náà.

Bákan náà ni a kò tíì le fìdí àwọn tó wà nídìí ìkọlù náà múlẹ̀.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí àwọn agbébọn ń ṣe ìkọlù sí àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Nàìjíríà.

Àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje ní Abuja, wọ́n kò tíì mọ iye ẹlẹ́wọ̀n tọ sálọ

Egbìrìn ọ̀tẹ̀ bí a ṣe ń pa iná ọ̀kan ni òmíràn ń rú.

Àwọn agbébọn tún ṣe ìkọlù sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje, Abuja ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Keje, ọdún 2022.

Àwọn agbébọn náà gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ ní nǹkan bí aago mẹ́wàá kọjá ogún ìsẹ́jú ṣìnà ìbọn bolẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ọ̀hún

Ìkọlù yìí ló ń wáyé lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ Ààrẹ Muhammadu Buhari.

Àwọn ará àdúgbò ibẹ̀ ní kò dín ní ogún ìṣẹ́jú tí àwọn agbébọn náà fi ń yìbọn láì dá ọwọ́ dúró tí ẹnikẹ́ni nínú àwọn kò sì láyà láti jáde ní ilé kóówá wọn.

Bákan náà ni wọ́n ní ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn agbébọn náà tún ju àdó olóró bọ́mbù sí inú ọgbà ẹ̀wọ̀n ọ̀hún láti fi tú àọn ènìyàn wọn tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀.

Inú fu àyà fu ni gbogbo àwọn tó ń gbé agbègbè náà wà báyìí.

Títí di àsìkò yìí, iléeṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ́n kò ì tíì sọ ohunkóhun nípa ìkọlù yìí.