You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọwọ́ EFCC tẹ ayédèrú ọ̀gá àgbà àjọ FBI
EFCC mú afurasí tó ń pe ara rẹ̀ ní ọ̀gá àgbà àjọ FBI
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC, ti gbe ayederu ọga agba ajọ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika, FBI, Adamu Yahaya Jiyaba lọ ile ẹjọ.
Jiyaba kawọ pọn rojọ niwaju adajọ N.I. Afolabi nile ẹjọ giga kan to wa niluu Lafia, nipinlẹ Nasarawa.
Ẹsun ti wọn fi kan afurasi naa ni pe o gbiyanju lu jibiti lẹyin to dinbọn gẹge bii ọga agba ni FBI lọna ati gba awọn eeyan.
Ẹsun naa ka pe “Iwọ Adamu Yayaha Jiyaba, ninu ọdun 2022 niluu Abuja gbiyanju lati wu iwa ọdaran lẹyin ti o fi orukọ rẹ sinu fọọmu kan pe iwọ ni Robert S. Muller, to jẹ ọga agba ajọ FBI.”
“Erongba rẹ ni pe ki awọn eeyan gba ọ gbọ gẹgẹ bii ọga agba FBI, nitori naa o ti ṣe si ofin to lodi si abala kẹtalata ofin to rọ mọ iwa ọdaran ti wọn gbe kalẹ lọdun 2015.”
Afurasi naa ni oun ko jẹbi ẹsun naa rara.
Adajọ ti wa sun ẹjọ naa si ọjọ kẹrindinlọgbọn ati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii, amọ afurasi naa yoo ṣi wa ni ọgba ẹwọn niluu Lafia titi di ọjọ igbẹjọ naa.
Ọwọ EFC tẹ afurasi mẹrinla mii
Ẹwẹ, ọwọ EFCC tun ti tẹ awọn afurasi onijibi mẹrinla niluu Isualaocha, to wa Awka, ni ipinlẹ Anambra.
Awọn afurasi naa ni Okeke Chibuzor, Arinze Makua Samuel, Ejiofor Oguchukwu, Onyekwelu Chibueze Martin, Charles Chinedu, Okolie Chinecherem Charles, Ekechi Chibuike, Ikechukwu Louis ati Okeke Oluebube.
Awọn to ku ni Onyekwelu Chukwurah, Odimgbe Chibuzor, Umeh Uchenna,Okeke Somtochukwu ati Odo Paul.
Lara awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ awọn afurasi ọhun ni ọkọ ayọkẹlẹ Lexus SUV meji, ẹrọ kọmputa alagbeka HP meji, ati ọpọlọpọ foonu.