Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ fun ipele quarter finals ni idije bọọlu
àwọn obìnrin ni Africa to n lọ lọwọ ni Morocco, WAFCON 2022, yoo bẹrẹ ni Ọjọru,
ọjọ kẹtàlá, oṣu Keje, yoo si pari ni Ọjọbọ.
Eyi n waye lẹyin ti orile-ede mẹrin (Burundi, Togo,
Uganda ati Burkina Faso), ti ja kuro ninu idije naa ni opin ọ̀sẹ̀ to kọja.
Àwọn orile-ede to kù ni Naijiria, South Africa,
Botswana, Zambia, Tunisia, Senegal, Morocco ati Cameroon.
Bayii ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ quarter final yoo ṣe lọ:
- Zambia vs Senegal - Ọjọru laago mẹfa ni papa ìṣeré
Mohamed V n'ilu Casablanca.
- Morocco vs Botswana - Ọjọru laago mẹsan-an alẹ́ ni
papa ìṣeré Moulay Abdellah, n'ilu Rabat)
- Nigeria vs Cameroon - Ọjọbọ, laago mẹ́fà irọlẹ ni papa
ìṣeré Mohamed V, n'ilu Casablanca)
- South Africa vs Tunisia -Ọjọbọ, laago mẹsan-an alẹ ni papa ìṣeré
Moulay El Hassan n'ilu Rabat.
Nkan to yẹ ki o mọ̀ nipa orile-ede kọọkan ti yoo gbá quarter final;
Copper Queens ti Zambia ati Teranga Lionesses ti
Senegal
Igba akọkọ niyii ti ẹgbẹ agbabọọlu orile-ede mejeeji
tayọ kọjá ipele akọkọ idije WAFCON, group stage. Ipele yii ni wọn ti má n pin
orile-ede kọọkan si isọri.
Nitori naa, o
nira diẹ lati sọ àsọtẹ́lẹ̀ nipa ẹni ti yoo bori ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn lọjọru.
Atlas Lionesses ti The Mares ti Morocco ati Botswana
Lootọ lo jẹ pe igba akọkọ niyii ti Botswana n kopa ni
idije Wafcon, amọ wọn ko ṣe e fi ọwọ rọ sẹyin.
Ẹwẹ, orile-ede Morocco naa to gbalejo idije ti ọdún
yii naa ko kẹ̀rẹ̀.
Wọn ko padanu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kankan lati igba ti idije
naa ti bẹ̀rẹ̀ ni isọri A ti wọn wa.
Ayo marun-un ni wọn ti gba wọlé. Eyi tó mu ki wọn ṣe
ipo kinni ni isọri wọn.
Super Falcons ti Naijiria ati Indomitable Lionesses ti
Cameroon
Igba mẹsan-an ni ẹgbẹ́ agbabọọlu obìnrin Naijiria,
Super Falcons, ti gba ife idije WAFCON, ninu igba mọkanla to ti waye. Lọwọ lọwọ,
ọwọ wọn ni ife naa wa lẹyin ti wọn bori lọdun 2018.
Ninu idije ti ọdun yii, Super Falcons fidirẹmi ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀
wọn àkọ́kọ́, pẹlubi South Africa ṣe lù
wọn ni 2-1.
Wọn padà bori ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn keji, nigba ti wọn
lu Botswana ni 2-0.
Bakan naa ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn kẹta, àmì ayo 4-0 ni wọn
lu Burundi.
Cameroon ni wọn o koju ni ipele quarter final. Ẹgbẹ́
agbabọọlu mejeeji kii ṣe àjòjì si ara wọn. Ipade wọn lori pápá ma n dà bi ti
erin meji ni.
Àwọn mejeeji lo koju ara wọn ni ipele quarter final lọdun
2016, n'ilu Yaounde lorilẹ èdè Cameroon.
Ẹgbẹ agbabọọlu Indomitable Lionesses naa ko ṣe fi ọwọ
yẹpẹrẹ mu lagbo bọọlu obìnrin ni Africa, sugbọn wọn ko ti laafaani lati gba ife
WAFCON ri lati igba ti wọn ti n kopa.
Banfana Banfana ti South Africa ati Carthage Eagles ti
Tunisia
Ẹgbẹ agbabọọlu Banfana Banfana ti South Africa, lo ṣe
ipo keji ni aṣekagba idije WAFCON lọdun 2018.
Lati ibẹrẹ idije ti ọdun yii si ni wọn ti n tayọ.
Wọn ko kuna idije kankan ní isọri C ti wọn wa. Àwọn lo
si wa ni ipo kinni pẹlu àmì mẹsan-án.
Ni iwoye eeyan, Banfana Banfana lágbára jù Chartage
Eagles ti Tunisia lọ l'ori pápá.
Amọ ohunkóhun lo le sẹlẹ ninu idije bọọlu.
Àwọn ẹgbẹ́ agbabọọlu to ba yege ni ipele quarter
finals, ni yoo lanfaani lati kopa ni idije bọọlu àwọn obìnrin ni agbaye, ti yoo
waye lọdun 2023 ni orile-ede Australia ati New Zealand.