You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn ọ̀nà tí o lè gbà láti ṣọ́ owó ná lọrí oúnjẹ lásìkò ọ̀wọ́ngógó yìí
Àwọn ọ̀nà tí o lè fi sọ́ owó ná lọrí oúnjẹ lásìkò ọ̀wọ́ngógó yìí rèé
Ni bayii ti aeto ọrọ aje Naijiria ti dẹnukọlẹ, ọwọngogo ounjẹ ti gbode, ọpọ araalu lo si n woye ohun ti wọn le ṣe lati koju ọwọngogo ounjẹ naa.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo ti n ṣe bi wọn ṣe mọ, ọpọ awọn mii lo ṣi n wa ọna lati ni owo diẹ lọwọ lẹyin ti wọn ba ra ounjẹ sile tan.
Idi ree ti BBC ṣe kan si onimọ nipa eto iṣuna, Oluwatosin Olasehinde, to jẹ oludasilẹ Money Africa ati Ladda.
Yatọ si onimọ yii, awọn eeyan mii tun ṣalaye fun BBC bi awọn eeyan ṣe le ṣọ owo na lasiko yii.
Awọn ọna naa ree
Ra awọn ohun to ṣe Pataki nikan
Asiko yii kii ṣe asiko ti eeyan n na owo ni inakuna, paapaa lori awọn nnkan ti ko ṣe pataki.
Ra awọn ohun ti o nilo nikan ti o ba lọ si ọja.
Ma ṣe fi ohunkohun ṣofo
Wa agolo ti o le maa fi wọn oujẹ ninu ile ki o to dana, ki o ma si se ounjẹ ti iwọ ati mọlẹbi rẹ ko ni le jẹ tan lẹẹkan ṣoṣo.
Ṣe atunṣe si irufẹ ounjẹ ti o n jẹ
Wo irufẹ ounjẹ ti o n jẹ ati awọn atunṣe ti o le ṣe si lọna ti o le fi jẹ ounjẹ ti yoo ṣe ara rẹ loore amọ ti ko ni wọn ju.
Fun apẹrẹ, ti o ba n fi ọpọ ẹran sinu ọbẹ rẹ tẹlẹ, o le maa lo ẹja tabi ẹyin bayii, titi ti nnkan yoo fi dẹrọ.
Ra ounjẹ pọ pẹlu awọn ẹlomiran
Kaka ki o da ra ounjẹ kereje sinu ile, o le maa ra oujẹ papọ pẹlu awọn idile miran ki ẹ si pin dọgba.
Ni imọ nipa ounjẹ ti o ni sinu ile
Rosie gba awọn eeyan nimọran lati yẹ inu ile wọn wo ki wọn to lọ ra ounjẹ ki wọn ma ba ra eyii ti wọn ni sinu ile tẹlẹ.
Ra ounjẹ nibi ti ko ti gbowo lori
O le lọ ra ounjẹ rẹ nile itaja ti owo ori ounjẹ wọn ko le kan eeyan leegun ẹyin.
Tabi ki o lọ ra ounjẹ nibi ti wọn ti n ta ounjẹ ni iye ti wọn n ta fun awọn alagbata.
Lo ẹrọ amounjẹ tutu rẹ daadaa
Kaka ki o maa da ounjẹ nu, o san ki o gbe irufẹ ounjẹ bẹẹ pamọ sinu ẹrọ amounjẹ tutu rẹ pamọ fun ọjọ miran.