Sisi Quadri, Rukayat Gawat, àtàwọn gbajúmọ̀ òṣèré àti olórin míì tó kú lọ́dún 2024

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Tibi tire ni a dá ilé ayé, kò sì ní ohun tó ní ìbẹ̀rẹ̀ tí kìí lópin, ikú lópin ẹ̀dá.

Ní ọdún 2024, bí àwọn èèyàn ṣe bímọ, tí wọ́n rẹ̀ sí i, náà ni àwọn èèyàn kan dágbére fáyé, tí wọ́n kí dúnìyàn pé ó dìgbà.

Èyí kò yọ àwọn èèkàn ìlú tàbí gbajúmọ̀ láwùjọ sílẹ̀ nítorí gbogbo ohun ẹlẹ́mìí ló dá agbádá ikú.

Nínú ìròyìn yìí ni a ti ṣe àkójọpọ̀ àwọn èèkàn ìlú, pàápàá lágbo eré tíátà tí wọ́n dágbére fáyé lọ́dún 2024.

Aderemi Adedeji (Olofa Ina)

Ikú àgbà òṣèré yìí, Aderemi Adedeji ni ó kọ́kọ́ milẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2024.

Alẹ́ Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹrin, oṣù Kìíní ọdún 2024 ni ìròyìn jáde pé àgbà òṣèré náà ti jáde láyé.

Ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin ni kí ọlọ́jọ́ tó ó dé.

Ọ̀kan lára àwọn ìyàwó bàbá Olofa Ina tó bá BBC News Yoruba sọ̀rọ̀ nígbà náà sọ pé, àgbà òṣèré náà ṣe àìsàn fún bíi ọ̀sẹ̀ mẹ́ta kí ọlọ́jọ́ tó dé.

Olofa Ina gbajúmọ̀ fún ìmọ̀ kíkún tó ní nípa àwọn òwe ilẹ̀ Yorùbá, tó sì má ń ṣe ìgbélárugẹ wọn nínú àwọn eré tó ti kópa.

Jimi Solanke

Gbajúgbajà akọ̀tàn àti asọ̀tàn, olórin ìbílẹ̀, akéwì, tó tún jẹ́ àgbà òṣèré ni Alàgbà Jimi Solanke nígbà ayé rẹ̀.

Ọdún 1942 ni wọ́n bí olóògbé náà sáyé.

Òwúrọ̀ kùtù ọjọ́ Ajé, ọjọ́ karùn-ún, oṣù Kejì ọdún 2024 ni Solanke dágbére fáyé ní ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ ìṣègùn Olabisi Onabanjo tó wà ní Sagamu ní ìpínlẹ̀ Ogun lẹ́ni ọdún méjìlélọ́gọ́rin.

Tolani Quadri Oyebamiji (Sisi Quadri)

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣe ní kàyéèfì nígbà tí ikú gbajúmọ̀ òṣèré àti adẹ́rìnínpòṣónú, Tolani Quadri Oyebamiji tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Sisi Quadri gbòde lọ́jọ́ kìíní, oṣù Kẹta ọdún 2024.

Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí ọjọ́ kejì tí fíìmù Anikulapo tí Sisi Quadri kópa gẹ́gẹ́ bí òkú ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde ni.

Ilé ìwòsàn LAUTECH tó wà ní ìlú Ogbomoso ni Sisi Quadri dákẹ́ sí lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́.

Ẹni ọdún márùndínláàdọ́ta ni Sisi Quadri jáde láyé.

John Okafor (Mr Ibú)

Ọjọ́ kejì, oṣù Kẹta ọdún 2024 ni gbajúmọ̀ òṣèré adẹ́rìnínpòṣónú lédè Gẹ̀ẹ́sì, John Okafor tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mr Ibú jáde láyé.

Ṣáájú kí ọlọ́jọ́ tó dé ni Mr Ibu tí ń ṣe àìsàn èyí tó mú kí wọ́n gé ẹsẹ̀ rẹ̀ kan ní oṣù Kọkànlá ọdún 2023.

Iṣẹ́ abẹ méje ni àwọn ẹbí rẹ̀ sọ pé ó ti ṣe kí wọ́n tó pinnu pé kí wọ́n gé ẹsẹ̀ rẹ̀ láti ri dájú pé ó wà láàyè.

Ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù Kẹwàá, ọdún ọdún 1961 ni wọ́n bí Mr Ibu tó sì dágbére fáyé lẹ́ni ọdún méjìlélógọ́ta.

Morenikeji Adeleke (Egbin Orun)

Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kejìdínlógbọn, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 ni ìròyìn ikú òjijì akọrin ẹ̀mí, Morenikeji Adeleke, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Egbin Orun sọ ọ̀pọ̀ sínú ìbànújẹ́.

Níṣe ni ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ké pé àwọn kò gbọ́ pé akọrin ẹ̀mí náà ṣe àárẹ̀ kankan kó tó di pé ọlọ́jọ́ mu lọ.

Ní ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kejì, ọdún 1985, ni wọ́n bí Egbin Orun èyí tó túmọ̀ sí pé ó jáde láyé lẹ́ni ọdún mọ́kàndínlógójì.

Ọ̀pọ̀ àwọn akọrin ẹ̀mí ẹgbẹ́ rẹ̀ ló ń fi ìwà ìtọrẹ àánú ròyìn Egbin Orun àti pé ó máa ń ṣe àtìlẹyìn tó gbòòrò fún àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀.

Ganiyu Akinpelu (Ogunjimi)

Òdú ni àgbà òṣèré Ganiyu Akinpelu kìí ṣe àìmọ̀ fólóko fáwọn olólùfẹ́ eré fíìmù abúlé pàápàá láàárín ọdún 1990 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000.

Ogunjimi Ajagajigi oògùn ni orúkọ tí ọ̀pọ̀ mọ̀ ọ́n sí nígbà ayé rẹ̀.

Ọmọ Ogunjimi, Ismaila Akinpelu sọ fún BBC News Yoruba pé oṣù mẹ́ta ni bàbá òun fi ṣe àárẹ̀ kí ọlọ́jọ́ tó dé fún un lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin ọdún 2024.

Ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin ni Ogunjimi lò láyé.

Dayo Adewumi (Sule Suebebe)

Lára àwọn ikú gbajúmọ̀ òṣèré tíátà tó fa awuyewuye ni ikú Dayo Adewumi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Sule Suebebe.

Níṣe ni àwọn kan gbé ìròyìn lẹ́yìn ikú rẹ̀ pé àwọn ẹbí rẹ̀ kọ̀ láti gba òkú rẹ̀ lọ́wọ́ pásítọ̀ Agbala Gabriel níbi tí títán dé ba sí, nílùú Ibadan.

Ọ̀pọ̀ ọdún ni Suebebe fi ṣàárẹ̀, tó sì wà ní ọ̀dọ́ pásítọ̀ Agbala Gabriel tí wọ́n ti ń tọ́jú rẹ̀.

Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀, Olufemi Adewumi ní ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, pé ìròyìn òfégè ni ìròyìn náà.

Ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin ni olóògbé Adewumi kí ọlọ́jọ́ tó dé.

Onyeka Onwenu

Gbajúmọ̀ akọrin olóhùn iyọ̀ ni Onyeka Onwenu nígbà ayé rẹ̀.

Onyeka Onwenu fi ayé sílẹ̀ ní ọgbọ̀njọ́, oṣù Keje ọdún 2024 lẹ́yìn tó kọrin tán níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan.

Ní ọdún 2021 ni Onyeka Onwenu ti ṣáájú kọ àkọsílẹ̀ nípa bí òun ṣe fẹ́ kí wọ́n sin òun lẹ́yìn tí òun bá lọ tán.

Ó ní ohun tí òun fẹ́ ni "ẹ gbàdúrà fún mi, ẹ ṣètò ayẹyẹ oúnjẹ ọ̀sán tàbí ti àṣálẹ́ fáwọn èèyàn, ẹ ṣàwàdà, ẹ dápàárá nípa mi, ẹ ṣe àjọyọ̀, kí kálukú sì gba ibi okoòwò rẹ̀ lọ lẹ́yìn náà."

Ọdún méjìléláàádọ́rin ni Onyeka Onwenu lò lórí ilẹ̀ ayé.

Aduke Gold

Ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹjọ ọdún 2024 ni akọrin ẹ̀mí Aduke Ajayi, Aduke Gold jáde láyé lẹ́ni ọdún mérìndínlógójì.

Àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara ni ẹ̀gbọ́n Aduke Gold, Pásítọ̀ Ajayi Aderounmu tó bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ní ó ṣekúpa akọrin náà.

Aduke Pẹnkẹlẹ ni ó kọ́kọ́ ń jẹ́ nígbà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ orin kó tó yipadà sí Aduke Gold lọ́dún 2008.

Ilé ìwòsàn UCH tó wà ní Ibadan ni Aduke Gold dákẹ́ sí táwọn ẹbí rẹ̀ sì fẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn náà pé àìbíkítà ló fa ikú akọrin ẹ̀mí náà.

Dele Gold

Ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2024 ni ariwo tún sọ lẹ́ka orin ẹ̀mí pẹ̀lú iku gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí mìiràn, Dele Agbeyo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Dele Gold.

Ikú Dele Gold ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn oṣù kan tí akọrin ẹ̀mí mìíràn, Aduke Gold dágbére.

Abẹ́ ìtọ́ni àgbà ọ̀jẹ̀ olórin Juju nnì Ebenezer Obey ni Dele Gold ti bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ.

Kò sí ẹni tó lè sọ pé nǹkan pàtó báyìí lé ṣokùnfà ikú Dele Gold.

Rukayat Gawat Osifeso

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Kẹsàn-án ọdún 2024 ni ìròyìn ikú gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí ẹ̀sìn Islam, Alhaja Rukayat Gawat Osifeso gbòde.

Níṣe ni ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ akọrin náà gbọgbẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà táwọn èèyàn sì ń kọminú lórí ohun tó ṣokùnfà ikú òjijì ọ̀hún.

Ní ìlú Ijebu-Ayepe ní ìpínlẹ̀ Ogun tó jẹ́ ìlú ọkọ Rukayat Gawat ni wọ́n sin òkú rẹ̀ sí lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun kan náà.

Rukayat Gawat Osifeso di gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí ẹ̀sìn Islam lẹ́yìn àwo orin tó ṣe fun bàbá rẹ̀, Alhaji Rasak Aremu Gawat nígbà tó ṣàdédé di àwátì lọ́jọ́ kẹwàá, oṣù Keje, ọdún 2012.

Ayobami Olabiyi (Bobo B)

Ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kẹwàá, ọdún 2024 ni gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Ayobami Mudashir Olabiyi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bobo B jáde láyé.

Àgbà òṣèré náà jáde láyé lẹ́yìn àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́.

Nígbà tó ń fìdí ikú náà múlẹ̀ fún BBC News Yorùbá, òṣèré, Toyin Adegbola ṣàlàyé pé láti bíi oṣù méjì sẹ́yìn ni Bobo B ti ń ṣe àárẹ̀ tó sì wà ní ilé ìwòsàn.

Toyin Adegbola ní oṣù méjì sẹ́yìn ni Bobo B ti kọ́kọ́ wà ní ilé ìwòsàn University College Hospital, UCH, Ibadan kí wọ́n tó gbé kúrò níbẹ̀ nígbà tí ara rẹ̀ kò balẹ̀ tó.

Abdulsalam Ishola (Charles Olumo Agbako)

Òwúrọ̀ Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá, ọdún 2024 ni Abdulsalam Ishola ẹni tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Charles Olumo Agbako, jáde láyé.

Ní ọdún 1923 ni wọ́n bí Charles Olumo Agbako sáyé tó sì papodà lọ́dún 2024 lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rùn-ún.

Agbako gbajúmọ̀ fún ipa líle tó máa ń kó nínú eré àtàwọn èdè òyìnbó ńláńlá tó máa ń sọ nínú àwọn fíìmù.