Wo nǹkan tó pa àgbà òṣèré, Adedeji Aderemi 'Olofa Ina'

Alẹ Ọjọbọ, ọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2024, ni iroyin jade pe agba oṣere, Oloye Adedeji Aderẹmi ti ọpọ mọ si Ọlọfa ina ti jade laye.

Eni odun metalelaadorin ni agba òoṣere naa ki ọlọjọ to de.

BBC Yoruba ti lọ sile oloogbe, nibi ti akọroyin wa ti ba awọn ẹbi sọrọ

Ọkan lara awọn iyawo oloogbe Aderemi to ba BBC sọrọ, Arabinrin Modinatu Aderemi, to tun jẹ iyawo kekere sọ pe ni nnkan bi aago meje aabọ alẹ Ọjọbọ ni ọkọ oun dakẹ.

O ni oloogbe ti wa ni idubulẹ aisan lati ọjọ pipẹ.

“Lati igba naa la ti n tọju wọn, to si wa nileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo to wa ni Fasiti Obafemi Awolowo niluu Ile-Ife.

“Irọlẹ Ọjọbọ ni wọn sọ ape ka ma a gbe wọn pada sile lati ileewosan. Amọ, ko ju bi ọgbọn iṣẹju ti a dele, ti baba ku.”

Eyi waye lẹyin ọsẹ bi mẹta ti agba oṣere naa ti wa nileewosan.

Arabinrin Aderemi sọ pe oun ko le sọ pato aisan to pa oloogbe, nitori pe kii ṣe irufẹ aisan kan lo n ṣe e .

O ni eeyan daadaa ni ọkọ oun, to si jẹ pe ko si nnkan to tobi ju ti ọkọ oun ko le fi ṣaanu.

“To ba jẹ nipa ti oore ati aanu ṣiṣe ni, ko yẹ ki ọkọ mi ti ku.

O ṣalaye pe ọkọ oun kii binu pẹ ju bo ṣe yẹ lọ.

"Koda, ti a ba ja, awọn ni wọn tun ma n gbe ibinu kuro lara mi."

Ọmọ oloogbe ni eeyan daadaa ni baba oun

Ẹnikan lara awọn ọmọbinrin Baba Olafa Ina, Arabinrin Suarau Adedeji Aderemi sọ fun BBC pe eeyan daadaa ni wọn mọ baba oun si ni adugbo.

O ni oloogbe ma n tọ ọpọ eeyan sọna to yẹ nipa imọran ati ilanilọyẹ.

Ẹlomii to tun ba BBC sọrọ sọ pe gbogbo awọn ọmọ ilu Ede ti kii fẹ wa sile, ni baba oun fi imọran mu wa sile.

“Oju ro baba , oun gan-an ko fẹ ẹ ku. Amọ, aisan la ri wo, ao ri ti ọlọjọ ṣe.”

Ẹ f'ójú sọ́nà lójú òpó yìí láti mọ bí nǹkan ṣe n lọ