Wo nǹkan tí àwọn òṣèré tíátà Yorùbá ń sọ nípa Baba Olofa Ina tó di olóògbé

Awọn oṣere tiata Yoruba ti n sọrọ nipa iha ti wọn kọ si agba oṣere Yoruba, Adedeji Aderemi ‘Olofa Ina’ to di oloogbe

Kaakiri loju opo ayelujara, paapa lori Instagram ni awọn oṣere naa ti n sọrọ nipa ohun ti awọn ko le gbagbe nipa rẹ.

Ati awọn agbaọjẹ ati awọn mii to ṣẹṣẹ n gbori nidi ere tiata,gbogbo wọn ni wọn ṣe idaro Baba Olofaina ti ọpọ ri gẹgẹ bi agbaṣa Yoruba ga ninu ere sinima ati ori itage.

Ẹgbọn mi, o di gbere...

Dele Odule to jẹ ogunagbongbo lagbo oṣere Naijiria wa lara awọn to fi ọrọ ikẹdun soju opo Instagram lati fi kẹdun iku Olofaina to dagbere faye.

O juwe oloogbe gẹgẹ bi ẹgbọn rẹ to si ni oun ro pe yoo ru u la ni ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ.

Odule ni titi lae lawọn yoo maa ṣe iranti rẹ.

Oun nikan kọ la ri ninu awọn oṣere tiata to sọ nipa Olofaina ninu awọn agbaagba oṣere.

Jide Kosoko naa fi ọrọ nipa Olofaina si oju opo rẹ.

Ninu apejuwe agbaọjẹ yi to ṣe, Kosoko sọ pe ''Ha,Baba Yoruba ti lọ!''

''Aye ti ẹ fi silẹ yoo ṣoro lati di pada. Sun re o Oloye Deji Aderemi''

Apejuwe ti Jide Kosoko ṣe nipa oloogbe Olofa ina yi ṣe rẹgi pẹlu ti aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere TAMPAN, Bolaji Amusan ti ọpọ mọ si Mr Latin.

Oun naa sọ pe ''O di gbere Olofa ina,Baba Yoruba''

Apejuwe baba Yoruba yi ko ṣẹyin ipa ribiribi ti Olofa Ina ko nidi igbelarugẹ aṣa Yoruba yala nipa ere tiata tabi to ba n kopa lori eto redio.

Owe, aṣamọ iwoye ati ọrọ iṣesi ọmọlouabi jẹ nkan ti Olofaina gbe larugẹ nibikibi ti wọn ba pe e si lati wa sọrọ tabi kopa ninu ere.

O jẹ ọkan lara awọn agba oṣere ti ere wọn maa n mu ki ori awọn ololufẹ aṣa ati iṣẹṣe Yoruba maa wu.

O kopa ninu awọn sinima to lamilaaka to si fi ipa to ko ninu wọn ṣe igbelarugẹ Yoruba.

Ninu awọn oṣere tiata to tun jẹ bi ọmọ si Baba Olofa Ina to kẹdun iku rẹ la ti ri Kunle Afod ati Odunlade Adekola.

Awọn aworan baba Olofa Ina ati awọn oṣere tiata mii