You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"2024 jẹ́ ọdún tí mi ò bẹ Ọlọ́run pé kí n la irú rẹ̀ kọjá mọ́"
Bi ọdun 2024 ṣe n kasẹ nilẹ, ọpọ eeyan lo n ṣe iṣiro bi wọn sẹ lo ọdun naa, ati awọn ipa to ni ninu igbesi aye wọn.
Ọdun 2024 jẹ ọdun ti awọn kan ko nii gbagbe lailai, boya nitori awọn rere to ṣẹlẹ si wọn tabi awọn nnkan buruku.
Bakan naa ni Naijiria, ọpọ eeyan ni ko le gbagbe ọdun naa paapaa nitori inira ọrọ aje, ọwọn ounjẹ, epo bẹtiro, ati awọn nnkan miran.
BBC ba awọn eeyan kan sọrọ lori bi irinajo ọdun naa ṣe lọ fun wọn.
Lara awọn to ba BBC sọrọ ni Arabinrin Christiana Abiodun to ni ọdun 2024 jẹ ọdun ti oun ko bẹ ọlọrun pe ki oun tun la iru rẹ kọja mọ, nipa ọrọ iṣuna.
"O ni ọdun naa jẹ ki oun ri ara oun gẹgẹ bi alaimọọṣe.
"Mo n ṣiṣẹ, a mọ o dabii pe mi o ṣiṣẹ. Gbogbo owo ti mo ri, ounjẹ nikan lo n ba a lọ.
Fun Ọgbẹni Sunday Fagbemi, o ni oun ṣaa dupẹ pe aṣiri ounjẹ jijẹ bo.
Arabinrin Kikelomo Oguntayo ni tiẹ sọ pe oun ṣaa dupẹ pe ẹnikẹni ko snu ninu ẹbi oun.
Ẹlomiran to tun sọrọ, Arakunrin Popoola Babatunde ninu ọrọ tiẹ sọ pe gbogbo nnkan ti oun pinnu lati ṣe ninu ọdun 2024 lo lọ leto-leto, botilẹ jẹ pe ilu le, to si kan gogo.