Ọkùnrin tó dáná sun ara rẹ̀ àti ìyàwó l'Ondo jáde láyé, ìyàwó dèrò ilé ìwòsàn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti ṣalaye bi ọkunrin kan ṣe pa iyawo rẹ nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ ni ileeṣẹ ọhun ti ṣalaye bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa ko darukọ awọn mejeji, bẹẹ ni ko mẹnuba ibi pato ti iṣẹlẹ ọhun ti waye, o ni ṣe ni ọkunrin naa tan obirin ọhun, ti wọn ko jọ gbe papọ mọ, wa sinu ile lati wa gbe apoti ti o n ko aṣọ si ko to da ina le awọn mejeji lori.

Ọlọpaa ni ọkunrin ọhun jade laye, nigba ti ina jo obinrin naa kọja ala.

Atẹjade naa ni "Ọkọ ati iyawo ni ọgbẹni lagbaja ati arabinrin lagbaja tẹlẹ ṣugbọn wahala bẹ silẹ laarin wọn, eyii to mu ki wọn tuka.

"Ọgbẹni lagbaja pe arabinrin lagbaja pe ko wa gbe apoti to n ko aṣọ si.

"Ṣugbọn nigba to de inu ile naa, ọgbẹni lagbaja bẹrẹ si n dukoko mọ arabinrin lagbaja pe oun yoo pa ara oun, lẹyin naa lo ti ilẹkun pe awọn mejeji yoo jọ ku papọ ni.

"Lẹyin naa ni ọgbẹni lagbaja mu epo ati iṣana to si dada le oun ati obinrin naa lori.

"Ọgbẹni lagbaja ku lẹsẹkẹse nigba ti ina jo arabinrin lagbajara pupọ."

Ọlọpaa fi kun pe ile iwosan mẹta ọtọtọ ni wọn ti gbe obinrin naa lọ fun ayẹwo laarin ọjọ meji pere.

Lẹyin naa lo gba awọn araalu ni imọnra pe ki wọn ṣọra fun ololufẹ oni jagidijagan.