You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ètò ìjọ Ọlọ́run tó làmìlaaka tó máa ń wáyé lóṣù Kejìlá ọdọọdún ní Nàìjíríà
Oriṣiiriṣii eto ijọ Ọlọrun to rinlẹ lo maa n waye loṣu Kejila lọ́dọọdun lorilẹede Naijiria.
Ọgọọrọ eeyan lo maa n peju pesẹ sibi awọn eto yii, koda, awọn ọmọ ijọ maa rinrin ajo wa si Naijiria lati ilẹ okeere fun awọn eto yii.
Awọn akanṣe eto yii maa n saba waye fun ọsẹ kan gbako lọdọọdun.
Wọnyii ni awọn eto ijọ Ọlọrun to làmìlaaka to maa n waye lọdọọdun loṣu Kejila ni Naijiria:
Shiloh
Eto Shiloh jẹ eto ṣọọṣi Living Faith Church ti ọpọ mọ si Winners Chapel to maa n waye lọdọọdun.
Shiloh bẹrẹ lọdun 1999 ni gbọngan Faith Tabernacle to wa niluu Ota ni ipinlẹ Ogun.
Biṣọọbu agba ati oludasilẹ ijọ Winners Chapel, Ọmọwe David Oyedepo, lo kede wi pe Ọlọrun lo foun pe ki oun bẹrẹ eto Shiloh nibi t'awọn ọmọ ijọ naa yoo ti maa pejọ lati wa oju Ọlọrun ati lati sin in.
Biṣọọbu Oyedepo ni Shiloh jẹ ori oke ti Ọlọrun ti maa farahan sí awọn eeyan to n sin in.
Bakan naa ni Biṣọọbu Oyedepo tun sọ pe Shiloh jẹ eto kan ti Ọlọrun ti n dasi ọrọ awọn eeyan to wa oju rẹ.
Biṣọọbu Oyedepo to jẹ oludasilẹ ijọ naa lo maa n saba waasu ni irọlẹ ojoojumọ ti eto naa ba ti n lọ.
Awọn pasitọ mii naa maa waasu ninu awọn isin to maa waye laarọ ati ni ọsan.
Ọpọ eeyan lo maa jẹri si agbara Ọlọrun lọdọọdun nibi eto naa.
Apero pẹlu Ẹmi mimọ ijọ Redeem (Holy Ghost Congress)
Lara awọn eto ijọ Ọlọrun to làmìlaaka to maa n waye lọdọọdun loṣu Kejila ni Naijiria ni eto Apero Ẹmi mimọ (Holy Congress) ti ijọ Redeem - RCCG.
Eto naa to n lọ lọwọ bayii jẹ ẹlẹẹkejilaadọrin iru rẹ.
Ogunlọgọ eeyan lo maa n peju pesẹ si ipagọ ijọ RCCG to wa lopopona ilu Eko si Ibadan eyi ti ọpọ eeyan mọ si 'Redeem Camp.'
Lara awọn eto to maa waye nibẹ iwaasu ọrọ Ọlọrun, fifi awọn pasitọ sori ijọ ati isin alẹ pẹlu Ẹmi mimọ eyi to maa kasẹ eto naa nlẹ lọjọ Ẹti.
Pasitọ E.A. Adeboye to jẹ adari ijọba RCCG lagbaaye lo maa ṣiwaju iwaasu nibi eto naa lọdọọdun.
Kaakiri agbaye l'awọn eeyan ti maa n wa fun eto naa lọdọọdun.
Ọpọ awọn alejo to maa n wa fun eto yii ni wọn maa ṣaba de si inu awọn ile itura to wa ni ipagọ ijọ RCCG ti eto naa ti n waye.
Awọn alẹnulọrọ láwùjọ at'awọn oloṣelu nla nla lo maa wa nibi eto yii lọdọọdun.
"The Experience"
Eto "The Experience" jẹ eto kan ti ijọ House on The Rock n ṣe agbatẹru rẹ niluu Eko.
Eto yii ti waye bayii fun ọdun mọkandinlogun ni gbagede Tafawa Balewa Square (TBS) ni ilu Eko.
Eto yii jẹ eto kan ti oniruuru awọn akọrin ẹmi ti maa n kọ orin pe ẹmi sọkalẹ nibi apejọ naa.
Pasitọ Paul Adefarasin to jẹ oludasilẹ ijọ House On The Rock lo maa n ṣe agbekalẹ eto yii lọdọọdun.
Gẹgẹ bi pasitọ Adefarasin ṣe ṣalaye, eto yii jẹ jade lati inu iran Ọlọrun nibi t'awọn eeyan yoo ti maa gbe okan ati ọwọ wọn ati ohun wọn soke lati yin Ọlọrun.
Alufaa naa ni ipejọpọ yii ko ni ṣe pẹlu ẹya, iran tabi ede kan.
Eto "The Experience" ti di gbajugbaja eto t'awọn eeyan niluu Eko fi maa n pari ọdun pẹlu awọn ilumọọka akọrin ẹmi.
Lati alẹ di idaji ọjọ keji ni eto yii maa n waye nibi t'awọn eeyan ti maa n yin Ọlọrun mọju.
Eto Imeko ijọ CCC
Eto Imeko CCC jẹ eto kan ti gbogbo ọmọ ijọ Sẹlẹ kaakiri Naijiria ati gbogbo agbaye maa n pejọ lati ṣe.
Ni ilu Imeko ni ipinlẹ Ogun ni ṣọọṣi ijọ Mimọ CCC ni eto naa maa ti n waye lọdọọdun.
Laarin ọjọ kọkanlelogun si ọjọ kẹtalelogun oṣu Kejila ni eto yii maa n waye lọdọọdun.
Lara awọn eto to maa n waye nibi ipejọpọ naa ni idije lori Bibeli, idije Ariyanjiyan, ere ori itage.
Oriṣiiriṣii iwaasu ni awọn ojiṣẹ Ọlọrun maa n fi balẹ nibi eto naa.
Ko tan sibẹ o, awọn idanilẹkọọ lori oniruuru iṣẹ ọwọ naa maa n waye nibi eto ọhun to maa n ṣẹlẹ lọdọọdun.
Eto tun wa fawọn ọdọ, awọn olori lẹkun jẹkun ati bẹẹ bẹẹ lọ.