Ìdí táwọn èèkàn Afenifere fi ṣ'àbẹ̀wò sí Farotimi l'ọ́gbà ẹ̀wọ̀n l'Ekiti

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn eekan ẹgbẹ Afẹnifẹre ti Alagba Ayo Adebanjo n dari, ti ṣabẹwo si Dele Farotimi, agbẹjọro ati ajafẹtọọ ti wọn fi si atimọle nitori ẹsun ibanilorukọjẹ l'Ekiti.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtala oṣu Kejila ọdun 2024 yii ni awọn ẹgbẹ to n ri si ọrọ iran Yoruba naa ṣabẹwo si Farotimi lọgba ẹwọn Ekiti to wa .

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, iṣẹ kan ti Alagba Adebanjọ ran si Farotimi, ni awọn ikọ to ṣabẹwo naa lọ jẹ fun un.

Bakan naa ni wọn si tun lọ lati beere nipa ilera agbẹjọrọ to wa lahaamọ naa.

Tẹ o ba gbagbe, Aarẹ Afe Babalola to jẹ agbẹjọro agba ni Naijiria lo fi ẹsun ibanilorukọjẹ kan Farotimi .

Ẹsun naa lo pada di ohun ti ile-ẹjọ paṣẹ, pe ki wọn fi Farotimi si ọgba ẹwọn na.

Ọmọ ẹgbẹ Afẹnifẹre ni Dele Farotimi naa n ṣe.

Ninu atẹjade kan ti igbakeji akọwe apapọ ẹgbẹ Afẹnifẹre, Alade Rotimi-John, fi sita ni ẹgbẹ naa ti koro oju si bi wọn ṣe fi Farotimi pamọ si ẹwọn.

"Ijakulẹ gbaa lo je, pe adajọ agba to gbọ ẹjọ naa lọjọ Iṣẹgun, kọ jale lati jẹ ki wọn gba beeli Farotimi, fun, ẹsun ti aaye oniduuro wa fun.

''Bi wọn ṣe ti Farotimi mọ ẹwọn lati ibẹrẹ ọrọ yii gan-an ti fihan pe idajọ ododo n ṣojojo,'' bayii ni apa kan atẹjade naa ṣe sọ.

Wọn fi kun un pe Afẹnifẹre yoo gbe igbesẹ to kan, lẹyin igbẹjọ mi-in ti yoo waye l'ogunjọ oṣu Kejila yii.

Diẹ lara awọn to ṣ'abẹwo naa ni Oloye Supo Shonibare, Basorun Segun Sanni, Abilekọ Nike Olujembola, Abilekọ Toyin Falade ati awọn mi-in.