Mọ̀ nípa Abiola Kayode afurasí ọmọ 'Yahoo' tí FBI mú lórí ẹ̀sùn jìbìtì N9bn l'Amẹrika

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ ọtẹlẹmuyẹ to n ṣiṣẹ iwadii lorilẹede Amẹrika, FBI , ti fi afurasi ogbologboo ọmọ orilẹede Naijiria kan, Abiola Ayorinde Kayode, ti wọn n wa fun jibiti ori ayelujara l'Amerika, ṣọwọ si Amẹrika lati orilẹede Ghana.

Ibi ti wọn n pe ni Nebraska, ni US gan-an ni wọn fi Abiola Kayode ranṣẹ si.

Atẹjade ti FBI fi sita, ṣalaye pe awọn gbe Abiola, ẹni ọdun mẹtadinlogoji to ti n fara pamọ si Ghana fun igba kan, lọ si Nebraska to ti ṣe yahoo, lati lọ jẹjọ ẹsun jibiti ayelujara ti wọn fi kan an.

Awọn alaṣẹ FBI sọ pe Kayode lu awọn eeyan ni jibiti ti owo rẹ ju $6 million (N9,307,380,000.00) lọ.

Ki i ṣe Nebraska nikan ni wọn lo ti lu jibiti ọhun, wọn ni kaakiri-kaakiri ni.

Ọna wo ni Kayode gba lu jibiti owo nla bẹẹ?

Gẹgẹ bi awọn to fẹsun kan Kayode ṣe ṣalaye, wọn ni ọmọkunrin yii pẹlu awọn kan ni wọn jọ n lu jibiti.

Wọn ṣalaye pe afurasi yii pẹlu awọn yooku rẹ jọ n ṣe bii ọga ileeṣẹ, igba mi-in, wọn yoo pe ara wọn ni aarẹ orilẹede, wọn si le ni awọn ni apaṣẹ okoowo to gbajumọ gidi kan.

Eyi ni wọn maa n lo ti wọn yoo fi wọle si ẹni ti wọn ba fẹẹ ṣe gbaju ẹ fun lara.

" Wọn maa n lo ẹka e-mail to maa jọ bii pe awọn ni wọn ni ileeṣẹ naa loootọ.

''Awọn ẹmẹwa Kayode yoo ni ki oṣiṣẹ tabi ẹni to ba gba lẹta naa fi owo ranṣẹ loju opo banki.

''Ẹni to gba lẹta email naa yoo ro pe gidi to ti ọdọ ọga awọn wa ni, yoo si fowo naa ranṣẹ, lai mọ pe wọn ti lu ileeṣẹ naa ni jibiti owo nla"

Bayii ni atẹjade FBI ṣalaye.

Wọn fi ẹsun kan Kayode, pe oun lo maa n fun awon onijibiti yoku ni akanti ileeṣẹ ti wọn yoo fi email ayederu naa ranṣẹ si.

Oun naa ni wọn lo maa n dari awon ileeṣẹ naa lati fowo ranṣẹ si akanti to ba fun wọn.

"Kayode ti orukọ rẹ wa ninu awọn eeyan ti FBI ti n wa tipẹ, ni a fẹsun kan, pe o n lo atẹjiṣe email kan; 'Business Email Compromise' (BEC).

"Lati oṣu kin-in-ni ọdun 2015 titi di oṣu kẹsan-an ọdun 2016.

''O ti lo BEC lati fi lu ọpọ ileeṣẹ lagbegbe Nebraska ati ibo mi-in ni jibiti owo to ju miliọnu mẹfa dọla lọ ($6 million.")

Bẹẹ ni atẹjade FBI ṣalaye.

FBI ti ran awọn akẹgbẹ Kayode kan lẹwọn

Ajọ FBI, fidi ẹ mulẹ pe ile-ẹjọ ti ṣedajọ awọn akẹgbẹ Kayode kan,wọn si ti gba idajọ ẹwọn.

Ẹwọn oṣu mẹrindinlọgọrun-un (96 months), ni won ju Adewale Aniyeloye si, ọkan lara awọn to n fi atẹjiṣẹ ayederu ranṣẹ si ileeṣẹ kiri ni.

Lati oṣu keji ọdun 2019 ni wọn ni Adewale ti wa nidii iwa to lodi sofin yii.

Bakan naa ni kootu paṣẹ fun un pe ko da $1,570,938.05 pada.

Pelumi Fawehinimi: Oṣu kẹta ọdun 2019 ni wọn ju u sẹwọn oṣu mejilelaadọrin (72 months).

Wọn ni ko da $1,014,159.60 pada ninu owo jibiti naa.

Onome Ijomone: Oun maa n fi ifẹ lu jibiti ni tiẹ ni bi won ṣe wi.

Wọn ju u si ẹwọn ọgọta oṣu (60 months) loṣu kin-in-ni ọdun 2020.

$508,934.40 ni won ni ko san lẹyin ti wọn gbe e wale lati Poland to wa.

Alex Ogunshakin: Oun naa maa n pese akanti ti wọn yoo lu ni jibiti ni.

Ẹwọn oṣu marundinlaaadọta (45 months) ni won ran an lọ loṣu kẹwaa ọdun 2024 yii, lẹyin ti won ri i mu ni Naijiria.

Awọn yooku ṣi n sa kiri, wọn o ti i ri wọn mu bi FBI ṣe ṣalaye.

Bí Kayọde ṣe rin ìrìn tiẹ̀

Oṣu kẹjọ ọdun 2019 ni awọn alaṣẹ Omaha, ni Nebraska, kọkọ fi ẹsun igbimọpọ lati lu jibiti ori ayelujra kan Kayode.

Loṣu kẹrin ọdun 2023, awọn agbofinro orilẹ-ede Ghana mu un, nigba ti ilẹ okeere ti ni ki wọn ba awọn fi ranṣẹ bi wọn ba ri i mu.

Gẹgẹ bi FBI ṣe ṣalaye, awọn alaṣẹ Ghana ṣe ohun ti America n fẹ, wọn si fa ọkunrin naa le awọn ọtẹlẹmuyẹ FBI lọwọ, awọn ni wọn gbe e lọ si Nebrasaka.

Ọjọ kọkanla oṣu Kejila ọdun 2024 yii lo kọkọ yọju si kootu l'America.

Adajọ Michael D. Nelson to gbọ ẹjọ rẹ si paṣẹ pe ki wọn ti i mọle titi di igba ti igbẹjọ miran yoo waye.