You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn olórí orílẹ̀èdè Araabu mẹ́fà tí wọ́n dojú ìjọba wọn bolè
Bashar al-Assad naa ti darapọ mawọn olori orilẹede ti wọn doju ijoba wọn bolẹ nigba ti wọn si wa lori aleefa.
Titi to fi di ọdun 2010, ko si ọkan ninu awọn olori orilẹede yii to le sọ pe nnkan maa yipada debi pe wọn o gbajọba mọ wọn lọwọ.
Bayii ni wọn bẹrẹ si ni gbajoba awọn orilẹede Araabu yii ni ọkọọkan ejeeji.
O si tun n ṣẹlẹ di oni pẹlu b'awọn ẹgbẹ alatako ṣe le Aarẹ Bashar al-Assad kuro lori oye.
Wọnyi ni awọn olori orilẹede Araabu ti wọn gbajọba mọ lọwọ:
Saddam Hussein (Iraq, 2003)
Saddam Hussein jẹ olori orilẹede Iraq tẹlẹ ri, oun ni olori abaṣẹ-waa àkọkọ nilẹ Araabu.
Lẹyin o rẹyin, wọn pada doju ijoba rẹ bolẹ ni.
Lẹyin ti ẹgbẹ al-Qaeda ṣe ikọlu si ile okowo agbaye niluu New York ati ile Pentagram ni Washington lọjọ kọkanla oṣu Kẹsan an odun 2001 ni aarẹ George Bush Amẹrika igba naa ti n gbero lati ko ọmogun yawọ Iraq.
Aarẹ Bush ni Saddam Hussein n ko nnkan ija oloro jọ.
Lọdun 2003 ni Amerika ko ọmogun ya wọ Iraq lati ibode orilẹede Kuwait.
Loṣu Karun un ọdun naa ni Amerika sẹgun awọn ọm'ogun Iraq, ti wọn si mu Hussein ẹni ti ile ẹjọ pada da ẹjọ iku fun.
Lẹyin ọdun mẹẹdọgbọn ni ijọba ni ile ẹjọ dajọ iku fun Saddam wi pe o jẹbi ẹsun iṣekupani niluu Dujail ati titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.
Zine al-Abidine Ben Ali (Tunisia, 2011)
Aarẹ Zine al-Abidine Ben Ali ni aarẹ akọkọ nilẹ Araabu ti araalu tako yọ nipo.
Zine al-Abidine Ben Ali to jẹ aarẹ Tunisia fún ọdun mẹtalelogun pada sa lọ Saudi Arabia lọdun 2011 lẹyin ti rogbodiyan gba gbogbo orilẹ-ède naa kan.
Iwọde bẹrẹ lẹyìn ti ọdọkunrin kan dana sun ara rẹ lọdun 2010 lẹyin tawọn ọlọpaa ṣe ikọlu si i.
Awọn oluwọde fẹsun kan aarẹ naa pe o kuna lati pese iṣẹ fun ọpọlọpọ araalu papaa julọ awọn ọdọ.
Bakan naa ni wọn tun fẹsun iwa ajẹbanu kan awọn to n ṣe ijọba pẹlu rẹ.
Hosni Mubarak (Egypt, 2011)
Ọgbọn ọdun ni Hosni Mubarak fi jẹ aarẹ orilẹede Egypt ki wọn to gba ijọba rẹ.
Bi wọn ṣe doju ijọba orilẹede Tunisia bolẹ lo ṣokunfa bi ijọba Aarẹ Mubarak naa ṣe wo lulẹ.
Mubarak kọwe fipo silẹ funra rẹ lẹyin ti araalu ti n ṣe iwọde fun ọpọlọpọ ọsẹ tako ijọba rẹ.
Awọn oluwọde ni ijọba rẹ kuna láti wa ojutuu si iṣoro airiṣẹṣe, oṣi ati iwa ajebanu.
Ali Abdullah Saleh (Yemen, 2011)
Iwọde to n ṣẹlẹ kaakiri ilẹ Araabu naa ni ọwọja rẹ de orilẹ-ede.
Lẹyin rogbodiyan to bẹ silẹ laarin araalu ati ijọba fun ọpọlọpọ oṣu ni Aarẹ Ali Abdullah gba lati fipo silẹ.
Abdullah gba lati gbe ijọba fun igbajeji lẹyin ikọlu ado oloro ni ileeṣẹ aarẹ.
Lọjọ kẹtalelogun oṣu Kọkanla ọdun 2011 ni Abdullah gbe ijọba silẹ lẹyin to farapa ninu ikọlu ado oloro to waye nile iṣẹ aarẹ.
Muammar Gaddafi (Libya, 2011)
Iwọde ati rogbodiyan to n ṣẹlẹ nilẹ Araabu naa de orilẹede Libya nibi ti Muammar Gaddafi ti ṣe ijọba fun ọdun mejilelogoji.
Gaddafi ni olori orilẹede akọkọ ti yoo ku lẹyin ti rogbodiyan ilẹ Araabu bẹrẹ.
Ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn ni Gaddaffi i ṣe nigba to di olori orilẹede Libya.
Lara ẹsun ti wọn fi kan Gaddaffi ni pe o n satilẹyin fawọn ọmogun alatako lawọn orilẹede mii.
Koda, wọn ni o lọwọ ninu ikọlu kan eyi to ja baalu ti ero 259 wa ninu rẹ ni Scotland lọdun 1988.
Ẹni ọdun mọkandinlaadọrin ni Gaddaffi nigba ti o ku.
Bashar al-Assad (Syria, 2024)
Bashar al-Assad ni aarẹ ti wọn sẹsẹ gba ijọba lọwọ rẹ nilẹ Araabu.
Lọjọ Aiku to kọja l'awọn ẹgbẹ ọm'ogun alatako le al-Assad kuro lori oye.
Ẹbi al-Assad ti ṣe ijọba orilẹede Syria fun ọdun mẹtalelaadọta ki wọn to doju ijoba Aarẹ Bashar bolẹ lopin ọsẹ to kọja.
Bashar di aarẹ Libya lọdun 2000 lẹyin ti baba rẹ ti kọkọ jẹ aarẹ fun ọgbọn ọdun.
O le ni aabọ miliọnu kan araalu to ti ku ninu ogun abẹle to bẹ silẹ ni Libya lati bi ọdun mẹrinla sẹyin.
Bakan naa, awọn eeyan bii miliọnu mejila ni wọn ti fi ilu silẹ.
L'Ọjọru ọsẹ to kọja ni ẹgbẹ alatako ṣẹgun ọmogun ijọba ni ilu Aleppo ti o si tun gba Damascus ti i ṣe olu ilu Libya naa.
Lẹyin o rẹyin ni a gbọ pe Assad ati ẹbi rẹ fẹ ṣe atipo lorilẹede Russia.