Orò tí kò bá ti fẹ́ rí ènìyàn, kó lọ sínú igbo – Oluwọ sọ̀rọ̀ lórí fífòfin de orò gbígbé ní Iwo

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ti sọrọ lori idi ti oun fi ni wọn ko gbọdọ gbe oro mọ ni ilu Iwo.

Lasiko to n ba BBC sọrọ ni oro ti wọn ba ti ni ki eniyan ma jade ni igba kankan ko ba igba mu.

Ninu ọrọ rẹ, kabiyesi ni awọn eniyan n lọ si ibi isẹ,wọn lo si oko, wọn lọ si ileewosan , nitori naa wọn ko fẹ ohun ti ko ni jẹ ki awọn araalu rin si ibi to ba wu wọn ati ni igba ti o ba wu wọn.

‘’Ko si ẹni to ni ki oloro mọ gbe oro rẹ, oye idile wọn ni ki wọn se ni ile wọn, ewleyii ti ko ba fẹ ri eniyan, ti ko fẹ ri ẹni kankan, obinrin, ọkunrin, tabi ọmọde, ẹ gbe lọ si inu igbo.’’

‘’Awọn dokita, nọọsi to n ṣiṣẹ ni oru, ti wọn fẹ ki ilu tuba ki o tuṣẹ, ko gbọdọ si oro to gbọdọ sọ pe ki eniyan ma jade.’’

‘’A ko fẹ mọ, ẹni to ba ṣe iru eyi yoo foju wina ofin.’’

‘’A ko fẹ mọ, ẹni to ba ṣe iru eyi yoo foju wina ofin.’’

Ọba Abdulrasheed ti ni ẹni to ba tun dan iru rẹ wo, to gbe oro pe ki awọn araalu mọ ri oun, tabi to da ẹnikẹni duro yoo foju wina ofin.

Kabiyesi ni idi ti oun fi gbe igbeṣẹ yii ni pe oro gbigbe naa n fa ija laarin ilu.

‘’Ti awọn onimoto ati awọn oloro ba pade ara wọn, ohun fa ija, ti wọn a si na wọn, ti wọn a si gbe wọn lọ si ibi kan.’’

‘’Awọn iwa to n da alaafia ilu ru a ko fẹ mọ, Oro ti ko ba ti fẹ ri eniyan ki o lọ si inu igbo’’

Bakan naa ni Oluwo ni gbigbe oro pẹlu gbedeke pe ki awọn eniyan ma jade n tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ, eleyii to ni ko ba igbalode mu ati iṣesi ọmọ ẹda.

‘’Se o tẹ ẹtọ awọn oniṣese mọlẹ lati ṣe ẹsin bo ṣe wu wọn? Ko si ijọba to ṣe ofin pe eniyan ko gbọdọ rin.’’

‘’ Mo n ṣe iṣese, amọ ohun to ba ti tako eledumare tabi ẹtọ eniyan, tabi ominira eniyan lati le rin lasiko to wu u, a ko ni fi aye gba.’’

‘’Kii se iṣese lo ni pe kii eniyan marin tabi jade ni ile, ko mu lakaaye wa’’

‘’Ki awọn araalu to ba fẹ ṣe oro idile, ki wọn sẹ ni inu ile wọn. Oro idile onikaluku yatọ si ara wọn, amọ oro to ba ti pa ọmọ eniyan lara, ko si aye fun mọ.’’

‘’Awọn ohun ti ko ba ti ba aṣa mu, ki wọn paa rẹ, iṣese ti ko ba ti ba igba mu mọ, ẹ daanu.’’

Wọn ma n pa eniyan ni aye atijọ, wọn ko pa eniyan mọ nitori igba ti yipada, ko si ohun to jọ bẹẹ mọ ti wọn ba n ṣe oro.

Oluwo ti ilu Iwo fikun pe awọn araalu ni oun ja fun nitori igbesẹ tuntun naa, ki alaafia le jọba ni ilu lai si rudurudu.

‘’Ọba ilu lo n wa alaafia fun awọn araalu, ko si asa ati iṣẹse to pe, amọ bi igba ba ṣe n lọ ni ki a maa tẹle’’