Bayo Lawal di igbákejì gómìnà Seyi Makinde ní Oyo

Adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ Oyo, Munta Abimbola ti búra wọlé fún Bayo Lawal gẹ́gẹ́ bí igbákejì gómìnà Seyi Makinde.

Ní ilé ọ́fíìsì ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ni ìbúrawọlé náà ti wáyé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Keje, ọdún 2022.

Ìbúrawọlé náà ló wáyé lẹ́yìn wákátì díẹ̀ tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo yọ igbákejì gómìnà Seyi Makinde tẹ́lẹ̀ Rauf Olaniyan nípò.

Lẹ́yìn tí wọ́n yan Olaniyan nípò ni wọ́n gba ìyànsípò Bayo Lawal gẹ́gẹ́ bí igbákejì Seyi Makinde.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, gómìnà Seyi Makinde rọ Lawal láti jẹ́ kí ìfẹ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Oyo jọba ní oókan àyà òun.

Ìgbìmọ̀ onídájọ́ tó ṣe ìwádìí mí ti gbowó, wọn kò sọ òdodo – Olaniyan

Igbakeji gomina ipinlẹ Oyo ti wọn ṣẹsẹ yọ nipo, Rauf Olaniyan ti sọrọ lori bi ile aṣofin ipinlẹ naa ṣe kede iyọnipo rẹ.

Olaniyan wa naka abuku si adajọ agba fun ipinlẹ Oyo, Adajọ Munta Abimbola pe o gbimọ ọtẹ lati ri pe wọn yoo oun nipo.

Olaniyan, ẹni ti o gba ẹnu agbẹjoro rẹ, Afolabi Fashanu, sọrọ lọjọ aje, ni igbimọ ti wọn gbe kalẹ lati ṣe iwadi oun, ni wọn ti gbe owo fun,

O ni idi ree ti wọn ko fi le sọ ododo ọrọ, ti wọn si gba ile aṣofin ni imọran pe ki wọn yoo oun nipo. O ni ohun ibanujẹ lo jẹ pe awọn igbimọ jẹ ki Makinde lo awọn fi ṣe isẹ buruku naa. “Iwadi awọn igbimọ ti Adajọ agba fun ipinlẹ Oyo gbe kale ni o kuna lati ni suuru, ti wọn si fẹ ṣe gbogbo re ni kiakia.

Ni akọkọ, Adajọ agba ni o tapa si ofin and ibura to gbe wọ ofisi to wa loni pẹlu bi o ṣe kẹyin si igbesẹ pe ẹjọ naa fẹ tẹsiwaju ni ile ẹjọ kotẹmilọrun.

O si tun fun awọn igbimọ naa lasẹ lati mu esi lọ si ile aṣofin ipinlẹ Oyo.”

“Eyi ni o lodi si ofin. Lori igbesẹ awọn igbimọ onidajọ naa, isẹ owo ti wọn san fun wọn, ni wọn ṣe.”

“Bawo ni wọn ṣe ma fi iwe ransẹ si igbakeji gomina laarọ ọjọ Ẹti laago mẹwa ku iṣeju mẹẹdogun, ti wọn si beere pe ko yọju si awọn ni ago mọkanla.

A fesi fun wọn pe igbakeji gomina nilo asiko lati gbaradi fun wọn sugbọn nitori pe wọn ti gba owo, wọn si fẹ ṣe isẹ owo naa.

Wọn da esi wa pada, ti wọn si joko ni ọjọ Satide, wọn si tun pari iwadi wọn lọjọ naa.”

“Iwa iyanijẹ gbaa leyi nitori a ro pe awọn eeyan pataki lo wa ninu igbimọ naa, a ri ẹniọwọ ninu wn pẹlu.

Bakan naa ni awọn Alhaji, ati awọn eeyan Ọlọrun miran wa nibẹ sugbọn o ti fi han pe a si jina si ijọba awarawa tootọ.”

Ilé aṣòfin Oyo yọ igbákejì gómìnà nípò

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ oyo ti yọ igbakeji gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ ẹrọ Rauf Olaniyan nipo rẹ loni ọjọ aje.

 Saaju nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti fi ẹsun marun un ọtọtọ kan igbakeji gomina ipinlẹ naa, Rauf Olaniyan.

 Mẹrinlelogun ninu awọn aṣofin ile naa lo tọwọ bọwe ẹsun naa, eyii ti wọn ka ni gbagede ile ọhun lọjọru.

 Gẹgẹ bii ohun to wa ninu iwe naa, lara ẹsun ti wọn fi kan Olaniyan ni aṣilo ọọfisi, iwa kobakungbe, ṣiṣi owo ilu na, aibọwọ fun awọn alaṣẹ, atawọn ẹsun mi

Agbẹnusọ ile, Adebo Ogundoyin lo kede ọrọ naa fun awọn ọmọ ile lẹyin ti awọn igbimo ẹlẹni meje ti wọn yan lati iṣe iwad lori esun ti wọn fi kan igbakeji gomina fun ile ẹsi iwadi ni.

Awọn igbimọ sọ fun ile ẹjọ pe Igbakekeji gomina ni kuna lati dahun si ipe wọn nigbati wọn ransẹ ni ọpọlọpọ igba ki awọn to fẹnupo lori abọ awọn fun ile.

Laipẹ yi ni ile ẹjọ to joko ni ibadan yii ẹjọ ti igbakeji gomina gbe wa si ile ẹjọ lati fi ofin de ile aṣofin Oyo lati ma ṣe yoo nipo.

Adajọ Ladiran Akintola ti Ile ẹj]ọ giga ipinlẹ Oyo lọ gbe igbẹjọ naa kalẹ.

Gomina Seyi Makinde ni ireti wa pe yoo kede Bayo Lawal gẹgẹ bi igbakeji gomina tuntun