You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléeṣẹ́ Innoson yóhùn padà lórí ₦3m tí wọ́n fún Mmesoma lẹ́yìn àbọ̀ ìwádìí
Ilé iṣẹ́ tó ń pèsè ọkọ̀ ní Nàìjíríà, Innoson Vehicles ti wọ́gilé owó mílíọ̀nù mẹ́ta Naira tí wọ́n ti ṣáájú ṣèlérí fún Mmesoma Ejikeme.
Mmesoma àti àjọ tó ń rí sí ìdánwò gbígba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sílé ẹ̀kọ́ gíga, JAMB ni wọ́n ń ṣe àríyànjiyàn láti bí ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn lórí iye máàkì tí akẹ́kọ̀ọ́ náà gbà níbi ìdánwò ọdún 2023.
JAMB ní máàkì 249 ni Mmesoma gbà àmọ́ Mmesoma ní 362 ni òun gbà àti pé òun ni òun gba máàkì tó pọ̀ jùlọ nínú ìdánwò náà.
Èyí ló mú kí ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láti ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà.
Ìgbìmọ̀ yìí ti wá gbé èsì àbájáde wọn síta tí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Mmesoma ṣèrú èsì ìdánwò rẹ̀ ni.
Lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ olùwádìí tí ìpínlẹ̀ Anambra gbé àbọ̀ ìwádìí rẹ̀ kalẹ̀ ni Iléeṣẹ́ Innoson kéde pé àwọn kò ní fún Mmesoma ní owó mílíọ̀nù mẹ́ta Naira láti fi tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí wọ́n ti kọ́kọ́ kéde.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Innoson, Cornel Osigwe fi sórí Twitter ní, ó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún àwọn pé àbọ̀ ìwádìí fi hàn pé Mmesoma ṣèrú èsì ìdánwò rẹ̀.
Wọ́n ní ìwà Mmesoma lòdì sí nǹkan tí iléeṣẹ́ àwọn dúró lé. Nítorí náà ni àwọn kò ní ṣe àtìlẹyìn fún ẹ̀kọ́ rẹ̀ mọ́.
Iléeṣẹ́ náà fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà tí Mmesoma hù da omi tútù sí àwọn lọ́kàn, àwọn kò ní kó àárẹ̀ ọkàn láti máa ṣe àtìlẹyìn tó tọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá fakọyọ.
Wọ́n ní gbígbé ètò ẹ̀kọ́ lárugẹ jẹ́ nǹkan tó jẹ ilé iṣẹ́ àwọn lógún.
Ìgbìmọ̀ olùwádìí sọ pé lóòtọ́ ni Mmesoma yí èsì ìdánwò JAMB rẹ̀ padà
Igbimọ oluwadii ti ijọba ipinlẹ anambra gbe kalẹ lati wadii ẹsun ṣiṣe magomago esi idanwo JAMB ti wọn fi kan akẹkọọ ẹni ọdun mọkandinlogun kan, ti pari iwadii rẹ.
Igbimọ naa sọ pe iwadii rẹ fihan pe lootọ ni Ejikeme Joy Mmesoma tun esi idanwo rẹ kọ.
Lati bi ọsẹ meji ni ariwo ti n waye lori esi idanwo Mmesoma, to fi iroyin sita pe oun gba 362 ninu idanwo UTME ti ọdun 2023, eyi to ni o jẹ maaki to pọ julọ.
Ni kete to fi esi naa sita, ni awọn kan ti fun ni ẹbun ẹkọ ọfẹ. Koda, ijọ̀ba ipinlẹ Anambra naa ti n gbero lati fun ni ami ẹyẹ, ko to di pe iwadii wọn lọdọ ajọ̀ JAMB fihan pe ayederu esi idanwo lo wa lọwọ Mmesoma.
Ajọ JAMB sọ pe 249 ni akẹkọọ naa gba, dipo 362 to sọ pe oun gba.
Eyi mu ki ijọba ipinlẹ Anambra bẹrẹ iwadii ọtun.
Gẹgẹ bi abọ iwadii ti igbimọ naa fi sita ni owurọ ọjọ Satide, wọn ni Mmesoma to jẹ akẹkọọ jade Anglican Girls Secondary School, sọ pe lara awọn nnkan ti awọn ri to mu ifura dani ni pe akọsilẹ ọjọ ibi, nọmba iforukọsilẹ, ibudo idanwo, ati bi esi idanwo to jẹ ti Mmesoma lati ọdọ JAMB yatọ patapata si eyi ti akẹkọọ naa fi sita ninu ayederu esi idanwo rẹ.
“Mmesoma Joy Ejikeme tun jẹwọ ninwaju ọga ile ẹkọ rẹ, ati akọwe fun eto ẹkọ, pe nnkan ti awọn oṣiṣẹ ajọ JAMB sọ ati akọsilẹ wọn, ni ojulowo bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.”
Bakan naa ni abọ iwadii naa fihan pe Mmesoma jẹwọ pe funra oun ni oun yi esi idanwo naa pẹlu nọmba Airtel ti Jamb si ojulowo esi rẹ ranṣẹ si.
Lẹyin naa lo lọ tẹ ayederu esi naa jade.
Wọn tun sọ ninu abọ iwadii naa pe iyalẹnu lo jẹ fun ọga agba ile ẹkọ anglican Girls Secondary School, Uruagu, Nnewi, ati akọwe fun eto ẹkọ ninu ijọ Anglica ni ẹkun Nnewi, nigba ti ọmọ na bẹrẹ si ni jẹwọ magomago to ṣe, ati bo ṣe tan awọn ẹbi rẹ, ile ẹkọ, ati ijọba ipinlẹ Anambra.
Ijiya wo ni igbimọ oluwadii sọ pe ki wọn fun Mmesoma?
Igbimọ oluwadii naa kọ sinu abọ rẹ pe ki akẹkọọ naa, kọ iwe ẹ̀bẹ̀ ranṣẹ si ajọ JAMB, ile ẹkọ rẹ, ati ijọba ipinlẹ Anambra ni kiakia.
Bakan naa ni wọn tun sọ pe ki Mmesoma lọ fun idanilẹkọọ ati igbani nimọran.