You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Afurasí ọkùnrin tó pa obìnrin ẹni ọdún 71, tó tún ta ọrùn ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ ní ìpínlẹ̀ Ogun bọ́ sọ́wọ́ Ọlọ́pàá
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ogun ti fi panpẹ ofin mu ọkinrin ẹni ọdun marunlelaadọta kan, to pa obinrin ẹni ọdun mọkanlelaadọrin, to si ta ẹya ara rẹ.
Iroyin ni afurasin naa, ọgbẹni Dauda Bello, pa arabinrin Mesesi Adisa, ko to ge ọwọ ati ẹsẹ rẹ, to si ta a fun ẹnikan to ti na papa bora bayii.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, wọn fi ṣikun ofin mu afurasi naa lẹyin ti obinrin ọhun dede poora lẹyin to fi ile silẹ lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii.
Lẹyin naa ni mọlẹbi oloogbe naa fi ọrọ ọhun lọ ni agọ awọn ọlọpaa to wa ni Sabo/Ilupeju.
Bi ọwọ ṣe tẹ afurasi naa
Ninu atẹjade, ọlọpaa ṣalaye pe “A tari ọrọ naa si ẹka to n ṣe iwadii ijinigbe nibi ti wọn ti ṣe iwadii to peye.”
“Lasiko iwadii naa, wọn tọpinpin ibi ti oloogbe naa lọ kẹyin, eyii to jẹ ile afurasi ọhun to wa lagbegbe Olodo, ni Imala, lẹyin naa ni wọn fi panpe ofin gbe lọ si agọ wa.”
Ninu iwadii ọlọpaa, afurasi naa ni owo fifi ọmọde ṣowo ẹru lawọn mejeji n ṣe, ọjọ si ti pẹ ti wọn ti mọ ara wọn.
O ni oloogbe naa wa si ile oun lati sọrọ lori owo ti wọn jọ n ṣe, amọ oun ṣakiyesi pe o gbe obitibiti owo dani.
Bello ṣalaye siwaju lagọ ọlọpaa pe nitori igbagbọ oun pe o gbe owo dani lohun ṣe la igi kan mọ oloogbe naa lori, to si daku rangbọndan.
O ni lẹyin naa ni oun gbe e lọ sinu igbo kan lati pari iṣẹ naa.
Gẹgẹ bii ohun ti afurai ọhun sọ, nigba to yẹ ara oku obinrin naa wo lo ṣakiyesi pe ẹgbẹrun mejilelogun pere lo wa lara rẹ lẹyin ti oun pa tan, inu oun si bajẹ.
Atẹjade Oyeyemi tẹsiwaju pe “Lẹyin to ri pe oun ko le ri ọpọ owo lara rẹ, o ge ọwọ ati ẹṣe rẹ, eyii to ni oun ti ta fun ẹnikan to ti na papa bora bayii.
Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti ni ki wọn gbe afurasi naa lọ sile ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan.