Àwọn Alátilẹyìn mí tótó ogún mílíọ̀nù lórí Ayélujára yóò dìbò fún mí - Funke Akindele

Gbajugbaja onitiata, Funke Akindele, ti ọpọ mọ si Jenifa, ti ni awọn alatilẹyin rẹ lori ayelujara toto ogun milọnu yo dibo fun ni bi eto idibo gomina ipinlẹ Eko ti o waye lọdun 2023,

Akindele, eni ti oludije gomina labe asia ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party, Abdul-Azeez Olajide Adeniran, kede gẹgẹ bi igbakẹji gomina rẹ, ni dundun ni ọsan so fun ẹgbẹ oṣelu naa nitori awọn ololufe rẹ wa lẹyin rẹ

Nigba ti o sọrọ lori momaworan Channels TV, Akindele oun ni igbagbo pe awọn ololufe ati awọn alatilẹyin oun sẹtan lati dibo fun oun ati Gomina, ti awọn si bori awọn lori awọn ẹgbẹ oṣelu yooku to ba di ọdun 2023.

O ni yato si awọn alatilẹyin lori ayelujara, Akindele ni awọn ololufe oun si pọ kaakiri origun mẹrin ipinlẹ Eko

“Mo ni awọn alatilẹyin ati awọn ololufẹ, mo mọn isoro wọn, mo nipa ariwo wọn, sugbọn nibayi, mo ti sẹtan lati fi opin si awọn isoro wọn.”

Gbajugbaja oṣere naa lo kede pe lootọ ni oun n dije du ipo igbakeji gomina ipinlẹ Eko labẹ Asia Peoples Democratic Party (PDP). lọjusẹgun ọse yii.

Funke Akindele ni oun n dije pẹlu oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Abdul-Azeez Olajide Adediran ti inagijẹ rẹ n jẹ Jandor.

Funke ni “pẹlu iriri iṣẹ mi gẹgẹ bi oṣere eyi to ti le ni ọdun marunlelogun, ati nipa ore ọfẹ Ọlọrun ti mo fi ṣe awọn nkan to laami laaka, mo ti ba awọn eeyan ṣiṣẹ kaakiri ti mo si ti ri iya ti awọn ti ko rọwọ họri n jẹ paapaa awọn ọdọ”.

Oṣere naa ni iṣẹ ti oun fẹ wa ṣe gẹgẹ bi igbakeji gomina ipinlẹ Eko ree lati bojuto yiyọ awọn ọmọde, ọdọ ati obinrin kuro ninu iya ati iṣẹ.

Ìdí tí mo fi yan Funke Akindele gẹ́gẹ́ bí igbákejì rèé - Jandor

Olùdíje sípò gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ní ìpínlẹ̀ Eko, Jide Adediran tí ṣàlàyé ìdí tó fi yan Funke Akindele gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀.

Ní bí ọ̀sẹ̀ kan sẹ́yìn ní ìròyìn ti kọ́kọ́ gbòde pé Jide Adediran ti yan Funke Akindele bíi igbákejì àmọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti agbẹnusọ Adediran jiyàn ọ̀rọ̀ náà.

Wọ́n ní lóòótọ́ ni orúkọ àgbà òṣèré náà wà lara àwọn orúkọ tí àwọn fà kalẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn kò ì tíì fẹnukò lórí ẹnìkan pàtó.

Ẹ̀wẹ̀, ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Keje ọdún 2022 ni Funke Akindele tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Jenifa fi fídíò kan léde tó fi kéde ìyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igbákejì olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko.

Akindele ni òun yóò fi iṣẹ́ tíátà sílẹ̀ ná fún ìgbà kan ná kí òun fi gbájúmọ́ òṣèlú.

Nígbà tó ń fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀, Adediran ní òun kò déédé yan òṣèré tíátà lásán bíkòṣe yíyan agbẹjọ́rò tó dáńtọ́ gẹ́gẹ́ bí igbákejì.

Ó ní yàtọ̀ sí eré ṣíṣe tí Funke Akindele fi gbajúmọ̀, ó ti ń pèsè iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ látara iṣẹ́ tó yàn láàyò láti ọdún pípẹ́.

Adediran ṣàlàyé pé òun ní ìgbàgbọ́ pé Funke Akindele yóò ní ipa rere lórí ìjáwé olúborí ẹgbẹ́ àwọn nínú ètò ìdìbò tí yóò wáyé lọ́dún tó ń bọ̀.

Ó fi kun pé nítorí Funke Akindele jẹ́ ènìyàn tí àwọn ará ìlú nífẹ̀ẹ́ lórí ayélujára tó sì mọ ohun tó ń lọ lẹ́sẹ̀ kúkù ni òun ṣe yàn án.

Ó ní ìbẹ̀rù ńlá ni àwọn méjéèjì jẹ́ fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Eko nítorí ọ̀tun tí yóò mú ìgbà ọ̀tun bá ìpínlẹ̀ náà ni àwọn dìde láti gba àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko kalẹ̀.

Ó ti Zeh! Funke Akindele kéde pé òun ń díjé du ipò igbákejì gómìnà Eko, ìdí rèé

Gbajugbaja oṣere, Funke Akindele ti ọpọ mọ si Jenifa ti kede pe lootọ ni oun n dije du ipo igbakeji gomina ipinlẹ Eko labẹ Asia Peoples Democratic Party (PDP).

Funke Akindele ni oun n dije pẹlu oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Abdul-Azeez Olajide Adediran ti inagijẹ rẹ n jẹ Jandor.

Akindele sọ eyi di mimọ ni owurọ ọjọ Iṣẹgun ninu fidio to fi sita lori ayelujara lati rọ awọn ara Eko ki wọn gbaruku ti i.

Ṣaaju eyi ni awuyewuye ti n lọ lode pe gbajugbaja oṣere yii ni Jandor yan ni igbakeji nigba tawọn eeyan bẹrẹ si ni ri aworan ipolongo wọn amọ ti ko fẹnu ara rẹ kede afi owurọ oni to fi fidio sita.

“Ẹyin eeyan mi l’Eko..., mo gbagbọ pe ó dara ki ẹ gbọ lati ẹnu emi ọlọrọ gangan nipa nkan ti mo fẹ gbe igbesẹ rẹ eyi ti mo woye gẹgẹ bi iṣẹ isin nla si awọn eniyan”.

Funke ni “pẹlu iriri iṣẹ mi gẹgẹ bi oṣere eyi to ti le ni ọdun marunlelogun, ati nipa ore ọfẹ Ọlọrun ti mo fi ṣe awọn nkan to laami laaka, mo ti ba awọn eeyan ṣiṣẹ kaakiri ti mo si ti ri iya ti awọn ti ko rọwọ họri n jẹ paapaa awọn ọdọ”. Oṣere naa ni iṣẹ ti oun fẹ wa ṣe gẹgẹ bi igbakeji gomina ipinlẹ Eko ree lati bojuto yiyọ awọn ọmọde, ọdọ ati obinrin kuro ninu iya ati iṣẹ.