Ta ni Ademola Bayonle, Olùdíje to kéré jùlọ t’o ‘n du ipò gómìnà Osun?

Ademola Bayonle Adeseye tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí DAB ni olùdíje tó kéré jùlọ tó ń dupò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun.

Ọmọ ọdún márùndínlógójì ni Ademola Bayonle tó sì ń rí ara rẹ̀ bí ẹni tó ń ṣojú àwọn ọ̀dọ́ nínú ìdíje sípò gómìnà náà.

Nínú oṣù Kẹwàá ọdún 1986 ni wọ́n bi ní Gbongan, ìjọba ìbílẹ̀ Ayedaade ní ìpínlẹ̀ Osun.

Ademola bẹ̀rẹ̀ ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ Staff School University of Ibadan, kó tó tẹ̀síwájú sí Command Day Secondary School, Ojoo, Ibadan láti kẹ́kọ̀ọ́ gírámà.

Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Ibadan ló ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó.

Lẹ́yìn èyí ló tẹ̀síwájú láti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè onípò kejì nínú ìmọ̀ ìlera ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Boston, Massachusetts, orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.

Ní ilé ìwòsàn Brigham and Women's Hospital ti ilé ìwòsàn olùkọ́ni Harvard, Massachusetts ni Ademola Bayonle ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alákòso ẹ̀ka Cilinical Data lọ́dún 2019.

Bákan náà ló jẹ́ ògbóǹtarigì onímọ̀ nípa ìwádìí.

Ademola Bayonle ni olùdásílẹ̀ àjọ aládani DAB foundation tó wà fún ìgbéga àti ìkúnpá àwọn ọ̀dọ́.

Ó darapọ̀ mọ́ òṣèlú láti dupò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun níbi ètò ìdìbò tí yóò wáyé lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Keje ọdún 2022 lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú YPP.