Gbajabiamila tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn Nàìjíríà lórí àwòrán tó fi léde

Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin, Femi Gbajabiamila ti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Gbajabiamila ń tọrọ àforíjì nítorí àwòrán rẹ̀ tó fi sórí ayélujára lánàá.

Ní àná ni Gbajabiamila fi àwòrán rẹ̀ kan pé òun ti wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Harvard ní ìlú London ṣọwọ́ sí orí ayélujára.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Gbajabiamila fi sorí ẹ̀rọ Twitter rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje ní àwòrán tí òun fi síta náà jẹ́ èyí tí kò tọ́ lásìkò tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga wà nílé kóówá wọn.

Ó ní ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì, ASUU àti ìjọba àpapọ̀ kìí ṣe ohun tó dùn mọ́ òun nínú.

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbésẹ̀ ni òun náà ti gbé láti fòpin sí ìyanṣẹ́lódì náà àmọ́ àwọn ń dúró dé kí ọ̀sẹ̀ méjì tí ìjọba fún àwọn Mínísítà láti fi parí ìyanṣẹ́lódì náà. 

Kí ni ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni Gbajabiamila fi àwòrán ibi tó ti wà ní ilé ẹ̀kọ́ Harvard níbi tí to tí ń kẹ́kọ̀ọ́.

Èyí ló fà á tí àwọn ènìyàn fi ń bínú wí pé lásìkò tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì ń yan iṣẹ́ lódì.