Wo àwọn àgbo ale, afàtọ̀ ìbílẹ̀ tí kò gba òǹtẹ̀ tí ìjọba ní ká ṣọ́ra fún

Ajọ to n ṣakoso ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria, NAFDAC, ti kilọ nipa awọn oogun ibilẹ kan to ti kun aarin ilu lai gba aṣẹ ijọba.

Ọga agba ajọ ọhun, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye, lo fi ọrọ naa lede fun awọn akọroyin niluu Abuja.

O ni awọn oogun naa ti awọn eeyan kan n kiri rẹ laarin igboro ni wọn ṣe ni agbo ati ẹfun ti awọn eeyan n fi simu.

Adeyeye fi kun pe awọn oṣiṣẹ NAFDAC ti fọn saarin igboro lati maa fi ṣikun ofin mu awọn to n po ifrufẹ agbo bẹẹ atawọn to n kiri rẹ lodi si aṣẹ ijọba.

Lara awọn oogun to sọ pe awọn n ṣiṣẹ lati ko kuro laarin igboro ni “Sacra Herbs.”

O ni “a ti bẹrẹ iṣẹ lati fi ṣikun ofin mu awọn to n po agbo ti wọn ko si gba aṣẹ lọwọ ijọba.”

“Nipa ti awọn to n po oogun tabi ko oogun ti ko gba aṣẹ ijọba wọ Naijiria, mo fẹ fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe a n ṣe gbogbo ohun ti a le ṣe lati ri pe oogun ati ounjẹ to gba ontẹ ijọba nikan ni wọn n ta laarin ilu.”

O pari ọrọ rẹ pe NAFDAC yoo gba awọn oṣiṣẹ tuntun siṣẹ ki wọn le fọ ilu mọ.

O ni “A tun n sa ipa wa lati ri pe a si afikun iye oṣiṣẹ ti a ni.”

“Nitori a nilo awọn oṣiṣẹ ti yoo maa lọ kaakiri igboro lati bojuto awọn oogun to n wọ aarin ilu.”