You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wọn kò lè jọba láì ṣètùtù kọ má lẹ́yìn nílẹ̀ Yorùbá- Aregbesola Anipupo
Oba Soun Ogbomoso: Ẹni tó fẹ́ jọba kìí ṣe òpònú, yóò ṣe ohun tó yẹ kí ìlú lè tùbà- Ifakore
BBC Yoruba bá àwon Oniṣẹṣẹ sọrọ lori fífí Pasitọ tabi Imamu jẹ Oba nilẹ Yoruba, ero wón ṣe ọtọọtọ.
Ayọjuran ló n mu ki pasitọ tabi imaamu jade dupo Oba ilẹ Yoruba nitori pe adé ìṣẹṣe ni ade ti Oba Yoruba n de sori.
ọkan lara awọn Oniṣeṣe naa ṣalaye fun BBC pe kí irinajo ọmọ oye to de ibi pe wọn maa faa kalẹ pe oun ni ori ade kan kii ṣe irinajo kekere.
Ati pe iru ọmọ oye bẹẹ yoo ti mọ nipa iṣẹṣẹ ati aṣa ilẹ Yoruba pẹlu ẹko nipa ori ade.
Onifade Ogundele to jẹ Oluwa Ifa Oke-Odo sọrọ nipa pataki bibọwọ fun enikeni ti Ifa ba ti mu nitori pe iru eni naa yoo ṣe daadaa.
Bawo ni ọrọ ṣe kan Pasitọ Adeboye Enoch?
Lasiko ti BBC n ba awọn Oniṣẹṣe sọrọ lori fifi onimọ ẹsin mii jóba ilẹ Yoruba naa ni Oluwo Ifakorede Alapoola ṣalaye pe oun ti maa n gbọ iwaasu ati ọrọ Baba Adeboye to jẹ baba ninu ẹsin igbagbọ ati ijọ Irapada fun Oba tuntun Soun ti wọn yan ni Ogbomoso.
O sọpe oun ko gbọ ki Adeboye bu Oniṣẹsẹ kankan ri ninu iwaasu rẹ tabi ko tabuklu aṣa Yoruba ri.
Ati pe fun idi eyi oun gabgbọ pe Ghandi ti wọn yan ni Soun tuntun yoo ṣe ohun to yẹ nipa bibọwọ fun eewọ, aṣa ati iṣẹṣe ilẹ Yoruba ni Ogbomoso ni kete to ba ti gba ade tan