You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba Taliban fòfin de àwọn obìnrin pé wọn ò gbọdọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nọ́ọ̀sì àti agbẹ̀bí mọ́
Iroyin to tẹ wa lọwọ lati orilẹede Afghanistan ti sọ pe ijọba Taliban to wa lode lorilẹede naa ti paṣẹ wi pe awọn obinrin ko gbọdọ kẹkọọ lati di nọọsi tabi agbẹbi mọ.
Ẹka eto ilera nikan ni ijọba Taliban ti fawọn obinrin lanfaani lati le lọ ile ẹkọ giga tẹlẹ lorilẹede Afghanistan.
Amọ, ni bayii ileeṣẹ iroyin orilẹede naa ti sọ pe ẹka ijọba to n ri si ọrọ ilera ti paṣẹ fawọn ile ẹkọ giga fasiti wi pe wọn o gbọdọ gbawọn akẹkọọbinrin laaye mọ fun ikẹkọọ nọọsi ati igbẹbi fawọn obinrin to ba fẹ bimọ.
Ọpọ fidio lo ti lu ori ayelujara pa eyi to ṣafihan bawọn obinrin lati ọpọ ile ẹkọ girama ti n sọ nipa igbesẹ ijọba yii.
Ni ṣe lawọn akẹkọọbinrin ile ẹkọ girama ọhun n sọrọ tako igbesẹ ijọba yii ninu awọn fọnran to wa lori ayelujara.
Ọpọ akẹkọọbinrin lo ti n lọ fun ikẹkọọ eto ilera tori ijọba Taliban ti fofin de wọn lati wọ ile ẹkọ girama ati ile ẹkọ giga fasiti.
Ijọba Taliban loun ko fẹ kawọn obinrin maa ṣi oju wọn silẹ mọ lori tẹlifisan
Ṣaaju ni ijọba Taliban ti paṣẹ fun awọn akọroyin lori ẹrọ amohunmaworan, lati ri pe wọn bo oju wọn lori afẹfẹ.
Agbẹnusọ ọlọpaa lori ọrọ ẹsin lo fi ikilọ naa lede fun awọn akọroyin.
Eyi n waye lẹyin ọsẹ meji ti wọn ti kọkọ paṣẹ pe gbogbo awọn obinrin gbọdọ maa wọ iboju ni ita gbangba abi ki wọn fi iya jẹ wọn.
Oriṣiriṣi ofin ni wọn fi de awọn obinrin to fi mọ pe wọn ko lee rin irinajo lai si ọkunrin ti yoo tẹle wọn, ti wọn ko si gba awọn obinrin laaye lati lọ sile ẹkọ.
Arabinrin akọroyin kan ti ko fẹ ki wọn darukọ rẹ ni ipaya ni eleyii jẹ fun awọn.
O ni "Ohun ti wọn n sọ ni pe ki a ma ṣiṣẹ ni oju ẹrọ amohunmaworan mọ''
''Nitori bawo ni mo ṣe fẹ ka iroyin pẹlu ẹnu mi ti wọn bo.''
''Mi o mọ ohun ti mo fẹ ṣe nitori mo gbọdọ ṣiṣẹ, ẹmi ni mo n pese fun awọn ẹbi mi.''
Agbẹnusọ ileeṣẹ Taliban to paṣẹ naa ni imọran ni oun gba wọn, amọ ti ko si ẹni to mọ nkan to le ṣẹlẹ si ẹni ti ko ba pa aṣẹ naa mọ.
Amọ awọn eniyan ti n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa, ti awọn ajafẹtọ si n sọ wi pe iboju ti awọn eniyan n lo lati dẹkun ajakalẹ arun ni awọn Taliban n lo lati fofin de awọn eniyan pe wọn ko gbọdọ ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ, afi ki wọn boju wọn.
Igba akọkọ ti wọn kọkọ gbe igbeṣẹ naa ni ọdun 1990 ti wọn gba ijọba, ti wọn si paṣẹ pe gbogbo obinrin gbọdọ bo oju ati gbogbo ara wọn, eleyii ti wọn n pe ni Burka, ni gbangba.
Ọdun 2001 ni orilẹede Amẹrika le ikọ Taliban jade kuro lori oye , ti awọn aṣẹ wọn si rọlẹ diẹ tawọn obinrin si bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lori ẹrọ amohunmaworan.