Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Kaka kewe agbọn dẹ, niṣe lo n le koko si lọrọ iwa ajẹbanu ni Naijiria o

Ki lo tun ṣẹlẹ?

Ajọ EFCC lo ma ti gbẹsẹ le ilegbe 753 nilu Abuja lọwọ oṣiṣẹ ijọba kan

Haha! Iyẹn tun gbẹnutan o. Ta ni wọn wa gba awọn ile ọhun lọwọ rẹ?

Ti o ba fẹ mọ, kan soju opo BBC.Com/Yoruba

Ọjọ buruku Eṣu gbomi mu

Lonii lo pe ọdun kan ti ileeṣẹ ọmoogun Naijiria ṣeesi ju ado oloro si abule Tudunbiri lapa Onipinlẹ Kaduna

Eyi to ṣeku pa ọpọ eeyan lasiko ayẹyẹ ọdun Mawludi awọn musulumi lọdun to kọja

Awọn ara abule ọhun ni iṣẹlẹ naa si n fun awọn ni ibanujẹ ọkan titi di akoko yii

Ẹni ọrẹ da ko ma fi ṣe ibinu, ẹni abinibi n da ni

Gbajugbaja oṣerebinrin, Ronke Odunsanya ti sọ pe ọrẹ oun timọtimọ kan

lo duro gẹgẹ bi eṣu lati da igbeyawo oun ru

Ronke tọpọ eeyan mọ si Flakky Ididowo ni oun ko le gbagbe iṣẹlẹ naa laelae

tori ibanujẹ lo maa n jẹ foun ni gbogbo igba