Àlàyé rèé lórí àwọn tí òfin owó orí tuntun kàn àtàwọn tó yọ sílẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Oni ọjọ kejidinlọgbọn, ọsu Kọkanla, ọdun 2024 ni ile aṣofin agba Naijiria yoo buwọlu abadofin owo ori tuntun.

Iroyin ni awọn aṣofin kan ti wọn kọkọ sọ pe awọn ko faramọ abadofin naa ṣaaju asiko ti yi ohun wọn pada bayii lẹyin ti igbimọ Aarẹ to wa nidi ofin ọhun ṣalaye awọn ohun kan to ṣokunkun ninu rẹ.

Wayi o, ijọba ti ni ofin tuntun naa ko wa fun lati gba owo lọwọ awọn ọmọ Naijiriati ko rọwọ họri.

Nigba ti awọn igbimọ to wa nidi ofin owo ori naa yọsi siwaju awọn aṣofin, wọn ni awọn olowo ilu ni ofin owo ori tuntun naa kan, ko kan awọn alaini.

Koda wọn ni ko si ohun to kan awọn ti owo ti wọn n pa wọle lọdun ko ba to miliọnu kan naira.

Ofin owo ori tuntun yii ko kan awọn alaini

Taiwo Oyedele, to jẹ alaga igbimọ to n ṣakoso owo ori tuntun naa ti sọ pe ko kan awọn alaini.

Nigba to n sọrọ niwaju awọn aṣofin, o ni awọn ọlọla nikan ni ọrọ naa kan, ati pe ofin ọhun tun waye lasiko yii lati ṣe atunṣe si kudiẹ-kudiẹ to wa ninu bi ijọba ṣe n pin owo ori ti araalu n san.

Oyedele sọ pe “Abadofin mẹrin to ṣe koko ni igbimọ yii gbe wa eyii ti afojusun rẹ jẹ lati ṣe atunṣe si eto owo ori wa.

“Ofin naa fẹ ko gbogbo ofin owo ori si abẹ ofin kan ṣoṣo, ki a mu irọrun ba bi araalu yoo ṣe maa san owo ori ki a si yọ awọn to n pa owo kereje kuro.

“Obadofin naa yoo ṣamulo bi a o ṣe maa fi imọ ẹrọ gba owo ori ati bi gbigba rẹ yoo ṣe rọrun.”

Lorin ọrọ bi wọn ṣe n pin owo ori to n wọle laarin awọn ipinlẹ, Oyedele sọ pe bi wọn ṣe n pin owo ori naa lọwọ yii fi sẹgbẹ kan.

O ni eyii ko bojumu latari pe awọn ipinlẹ ti ọọfisi olu ileeṣẹ nla-nla wa nikan lo n gbadun rẹ.

Ọrọ naa ko kan aralu to n pa owo to din ni miliọnu kan wọle lọdun

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ofin tuntun naa ko ni kan awọn ti owo ti wọn n pa wọle ko to miliọnu kan nairalaarin ọdun.

O ni “Lonii, a n gba owo ori lọwọ ẹni to n gba ₦30,000 loṣu, o n tumọ si pe irufẹ ẹni bẹẹ n pa ₦1,000 pere lojumọ, bawo ni eeyan ṣe le bọ ara rẹ pẹlu ₦30,000 lodidi oṣu kan?

“Ti irufẹ ẹni beo ba tilẹ n danikan gbe gan, yoo ṣaa wọ ọkọ, yoo ra ounjẹ, yoo san owo ile, bẹẹ ni yoo san owo ina mọnamọna. Nitori naa ko le rọrun fun wọn.

“Idi ree ti a fi n daba ofin pe ẹnikẹni to ba n pa ₦800,000 lọdun, pẹlu ₦200,000 gẹgẹ bii owo ile, ti apapọ rẹ jẹ bii miliọnu kan naira, pe ki irufẹ ẹni ma maa san owo ori mọ.

Wayi o, awọn araalu kan ṣi gbagbọ pe ilu le lọwọ yii, nitori naa kii ṣe asiko yii lo yẹ ki ijọba maa ronu ọna ti yoo fi gba lọwọ araalu.