‘Àwọn ọ̀dọ́ Yorùbá ṣetán láti gbèjà Niger tí àwọn olórí ilẹ̀ Adúláwọ̀ bá filè kógun ja Niger’

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ẹgbẹ́ tó ń pè fún ìdádúró ilẹ̀ Yorùbá ìyẹn Yoruba Self-Determination Movement (YSDM) ti rọ ìjọba Nàìjíríà àti àjọ ECOWAS lápapọ̀ láti má kógun ja orílẹ̀ èdè Niger.
Ẹgbẹ́ náà nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi síta látọwọ́ alága wọn, Ọ̀jọ́gbọ́n Banji Akintoye lẹ́yìn ìpàdé tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀ èdè olómìnira Benin ní àwọn kò faramọ́ kíko ogun ja Niger nítorí tí àwọn ológun gba ìjọba ní orílẹ̀ èdè náà.
Àtẹ̀jáde náà ní gbogbo àwọn ọmọ Yorùbá ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà tó fi mọ́ àwọn tó wà ní Kwara, Kogi àti ìpínlẹ̀ Delta ló panupọ̀ láti dá sí awuyewuye ọ̀rọ̀ òṣèlú tó ń lọ ní orílẹ̀ Niger.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye ní gbogbo àwọn nǹkan tó ti ń lọ lórí ayélujára láti ìgbà tí àwọn ológun ti gba ìjọba ní Niger fi hàn pé àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè náà faramọ́ bí àwọn ológun ṣe gba ìjọba orílẹ̀ èdè ọ̀hún.
Ó ní fún ìdí èyí, níṣe ló yẹ kí wọ́n fi àwọn ènìyàn sílẹ̀ láti ṣe ohun tó wù wọ́n pẹ̀lú orílẹ̀ èdè wọn ni.
Ó ṣàlàyé pé ọmọ ìyá ni àwọn orílẹ̀ èdè tí Hausa àti ẹ̀yà Yorùbá bá pọ̀ sí ní èyí tí Niger jẹ́ ọ̀kan nínú wọn àti pé ṣaájú kí àwọn òyìnbó tó wọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni Yorùbá àti Hausa ti ń ṣe papọ̀.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye ní ọ̀pọ̀ ọmọ Yorùbá ló ń gbé ìgbé àláfíà ní ilẹ̀ Hausa tí àwọn Hausa náà sì ń gbé ìgbé ìdùnnú ní ilẹ̀ Yorùbá nítorí náà àwọn fẹ́ kí gbogbo ayé mọ̀ pé [[awọn kò ní gbà kí ìkọlù kankan wáyé sí ìran Hausa.
Bákan náà lọ fi kun pé àwọn ọ̀dọ́ Yorùbá ló ní àwọn ti ṣetán láti lọ gbèjà orílẹ̀ èdè Niger bí wọ́n bá fi lè gbèrò láti lọ kógun ja orílẹ̀ èdè náà.
“Fún ìdí èyí, à ń rọ ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu láti wọ́gilé èròńgbà láti kógun ja orílẹ̀ èdè Niger, á fẹ kó yọ èrò náà pátápátá.”
“Bákan náà ni a tún rọ̀ ọ́ láti yí gbogbo òfin tí Nàìjíríà fi de Niger padà lórí àwọn ológun tó gba ìjọba ní orílẹ̀ èdè náà.”














