Ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní gba ìdámẹ́wà owó orí lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni tó bá jẹ tẹ́tẹ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ijọba Ghana ti fi ikede lede pe ẹnikẹni to ba ta tẹtẹ, to si jẹ yoo maa san idamẹwa fun ijọba orilẹede naa.

Ileeṣẹ ton risi ọrọ owo ile labẹle lo fi ikede naa lede, ti wọn si ni awọn yoo maa san owo naa ki wọn to fun ẹni naa ni owo to jẹ.

Ninu ọrọ naa, ijọba ni ẹnikẹni ti wọn ba gbẹṣẹ le ohun to jẹ, ti wọn si da owo rẹ pada, o ṣeeṣe ko ma san owo.

Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ tẹtẹ naa ni ijọba ti paṣẹ fun ki wọn maa fi si ori ẹrọ ayelujara wọn, iye ti awọn yoo ma gba lọwọ ẹni to ba jẹ tẹtẹ.

Kọmiṣọnna fun ọrọ owo ori, Edward Gyambrah ni owo ori ti wọn ba yọ labẹle naa yoo mu ki owo ori to n wọle ni abẹnu gbooro si.

Amọ awọn ọdọ orilẹede naa ti bu ẹnu atẹ lu igbeṣẹ ijọba lati maa gba owo ori lọwọ awọn to jẹ tẹtẹ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn ọdọ naa ni tẹtẹ ni awọn fi n rọpọ aisi iṣẹ to gbode kan lorilẹede naa.

Nibayii, ijọba ti kilọ fun awọn ileeṣẹ to n ta tẹtẹ wi pe awọn yoo fofin de wọn ti wọn ba gbe igbeṣẹ tako idamẹwaa naa.

Laipẹ yii ni ijọba Ghana ri owo iranwọ ọlọdun mẹta gba lọwọ Ajọ iranwọ owo lagbaye, IMF lẹyin ti ọrọ aje orilẹede naa dẹnukọlẹ.

Awọn adari eto ọrọ aje naa wa rọ ijọba lati fi owo kun owo ori, ki eto ọrọ aje orilẹede naa le gbooro si ni abẹle.