Lady killed and womb alleged removed: Lẹ́yìn wákàtí 48 tó gboyè nípa nọ́ọ̀sì, òkú Boluwatife ni wọ́n rí tí wọ́n ti yọ ilé ọmọ rẹ̀ lọ
Lopin ọsẹ to kọja ni iroyin kaakiri pe wọn ri oku dọbinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ọmọniyi Boluwatifẹ, ti awọn iroyin kan si sọ pe awọn ẹni ibi to gba ẹmi rẹ tun yọ ile ọmọ rẹ lọ.
Iroyin sọ pe akẹkọjade fasiti Lead City to wa nilu Ibadan ni ipinlẹ Ọyọ ni Boluwatifẹ; ko si tii ju wakati mejidinlaadọta ti wọn gba wọle sinu igbimọ awọn akọṣẹmọṣẹ itọju alaisan, nọọsi ati agbẹbi lorilẹede Naijiria.
Taa ló pa Boluwatife tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Nọ́ọ̀sì, tó tún yọ nǹkan lọ lára rẹ n'Ibadan
Iroyin sọ pe wọn ri oku rẹ lẹyin to lọ si ibi ayẹyẹ kan lati ṣe ajọyọ didi akọṣẹmọṣẹ nọọsi.
Ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹjọ ni wọn ri oku Boluwatife, ti awọn ẹ̀yà ara rẹ kan ti di awati.
Ninu fidio kan to n lọ kaakiri lori ayelujara, o han pe wọn la ikùn rẹ ki wọn to yọ awọn ẹya ara rẹ kan lọ, ti wọn si fi aṣọ bo o pada.
Awọn iroyin kan sọ pe ile ọmọ to wa ninu rẹ ni wọn yọ, àmọ́ a ko le fidi eyi mulẹ.
Lẹyin ti iroyin iku Boluwatife jade sori ayelujara, ni àwọn ọmọ Naijiria ti n kesi ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe iwadii.
Agbegbe Dandaru ni Mọkọla ni wọn ju oku rẹ si
Ẹni ti o jẹ akọwe adugbo naa, Alhaji Yẹkini Alausa ṣe alaye wi pe ọmọ daadaa ni wọn mọ Boluwatifẹ si ni adugbo, nitori jẹjẹ rẹ lo maa n lọ.
O ni lojiji ni awọn gbọ iroyin wi pe "wọn ti da emi Boluwatifẹ legbodo, wọn si ju oku rẹ si agbegbe Dandaru ni ọna Mọkọla."
Alausa fi idi ọrọ mulẹ wi pe Boluwatifẹ ati iya rẹ ni wọn jọ n gbe ile naa ni gbogbo igba ti o ba wale lati ile ẹkọ giga ti o wa.
Ọsẹ to kọja ni Bolu kẹkọgboye imọ ijinlẹ nọọsi ati agbẹbi ni fasiti - Ọrẹ Boluwatifẹ
Ọkan lara awọn ọrẹ Boluwatifẹ ti o tun jẹ ọmọ ile ijọsin kan naa pẹlu rẹ, Tijani Oluṣegun ṣe alaye wi pe ọsẹ to kọja ni Boluwatifẹ kẹkọọ gboye Nọọsi ni fasiti Lead City nilu Ibadan, bẹẹ sini o ṣe idupẹ ni Ṣọọṣi ti wọn jọ n lọ.
O ni nnkan iyalẹnu lo jẹ bi oun ṣe dede ri iroyin lori ayelujara wi pe wọn pa Boluwatifẹ lẹyin ti wọn kuro nibi ile ijo kan ti wọn ti lọ ṣe ayẹyẹ ikẹkọọjade, ti awọn olubi ẹda naa si yọ ile ọmọ rẹ lọ.