You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tó bá ọ̀rẹ́kùnrin lọ ilé ìtura kú śibẹ̀
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bayelsa ti fidi rẹ mulẹ pe ọmọ ọdun mẹrinla kan, Shallon Ebitare ku sile itura kan niluu Yenagoa.
Iroyin ni ọrẹkunrin oloogbe naa to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun, Lucky Okubo, lo gbe lọ sile itura naa.
A gbọ pe inu ile iwẹ to wa ni yara ti wọn gba nile itura naa ni Shallon ti ṣubu lulẹ, ko to jade laye.
Lẹyin iṣẹlẹ ọhun ni wọn gbe ọmọdebirnin naa lọ sile iwosan ijọba apapọ Federal Medical Centre (FMC) ilu Yenagoa, nibin ti dokita ti sọ pe o ti ku.
Iwadii fi han pe Shallon ati Lucky ti n fẹ ara wọn fun oṣu diẹ ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.
Wayi o, ileẹṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti fi ṣikun ofin mu Lucky lori ẹsun ipaniyan.
Agbenusọ ileeṣẹ naa ni Bayelsa, ASP Musa Muhammed, sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati wa kulẹkulẹ ohun to ṣokunfa iku ọmọdebinrin ọhun.
Muhammed ni “ni kete ti ọrọ naa to wa leti ni a lọ mu afurasi ti a gbagbọ pe o mọ nipa iku ọmọ ọdun mẹrinla naa to jẹ olugbe agbegbe Akaibiri, ni ijọba ibilẹ Yenagoa.
“Afurasi sọ fun wa pe asiko ti oloogbe lọ sile iwẹ lati bu omi si ara lo ṣubu to si farapa.”
Lẹyin ti Shallon ṣubu ni Lucky ke gbajare si alakoso ile itura naa ti wọn si gbe Shallon lọ sile iwosan nibi ti wọn ti sọ pe o ti jade laye.
Ọlọpaa pari ọrọ rẹ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ ohun to pa ọmọ ọdun mẹrinla naa.