Lẹ́yìn ò rẹyìn, èèyàn 51,447 ni yóò lọ fún Hajj lọ́dún yìí láti Nàìjíríà

Ajọ NAHCON to n ri si irinajo lọ si Hajj lorilẹede Saudi Arabia ti kede pe eeyan 51,447 ni yoo lọ fun eto Hajj lati Naijiria lọdun 2024 yii.

Adari ajọ NAHCON, Jalabi Arabi lo fidi ọrọ yii mulẹ niluu Abuja, eyi ti ajọ naa tun fi sori oju opo ayelujara X rẹ.

Ọgbẹni Arabi sọ pe ajọ NAHCON yoo gbiyanju lati jẹ ki eto Hajj ọdun yii kẹsẹ jari lai ni idiwọ kankan.

Ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe owo gọbọi lawọn musulumi san lati lọ fun iṣẹ Hajj ti ọdun yii.

‘’Ipalẹmọ Hajj ọdun 2024 yii lo tii nira julọ ni Naijiria.

Tẹlẹ, a maa n ni akoko lati ṣe eto to mọyan lori, amọ, lọtẹ yii, ijọba Saudi ko fun wa ni asiko to to lati ṣeto,’’ Arabi lo sọ bẹẹ.

Adari ajọ NAHCON tun ṣalaye pe ijọba apapọ ṣe iranwọ fun ajọ naa ni oriṣiiriṣii ọna lati ri pe eto Hajj ọdun 2024 kẹsẹ jari.

Gbedeke eeyan 95,000 ni ijọba Saudi Arabia fun Naijiria wi pe wọn le wa fun eto Hajji ọdun 2024.