You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ìwúlò káàdì ìdánimọ̀ Nàíjíríà tuntun tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti ṣe agbakalẹ kaadi idanimọ tuntun eleyii tawọn araalu le maa fi sanwo fun awọn nnkan ti wọn ba nilo.
Ajọ to n ri si kaadi idanimọ ni Naijiria, NIMC ni yoo ṣe agbatẹru kaadi ọhun.
Ajọ NIMC yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu banki apapọ Naijiria, CBN ati ajọ NIBSS to n ṣiṣẹ pẹlu awọn ile ifowopamọ lati gbe kaadi naa jade.
Ọgagba ẹka ibaraẹnisọrọ ni ajọ NIMC, Ọgbẹni Kayode Adegoke lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ẹti.
Ofin ajọ NIMC nọmba kẹtalelogun ọdun 2007 ṣe atilẹyin fun ajọ naa lati ṣe kaadi idanimọ gbogbonṣe fawọn ọmọ Naijiria.
Kaadi yii yoo fawọn araalu lanfani lati maa lo nnkan ijọba ati ti aladani bakan naa.
Kaadi idanimọ tuntun yii yoo tun ro awọn ọmọ Naijiria lagbara, ati pe yoo tun fun wọn lanfani lati kopa ninu idagbasoke orilẹede Naijiria.
Awọn to ba jẹ ojulowo ọmọ Naijiria ti wọn si ni kaadi NIN nikan ni yoo lanfani lati gba kaadi idanimọ tuntun yii.
Ara anfani to wa ninu kaadi idanimọ tuntun yii ni pe awọn araalu yoo le maa fi gba owo tabi san owo bii kaadi ATM tori wọn yoo ti so o mọ akaunti banki ẹni to ba n lo o.
Awọn to ba tun ni kaadi yii yoo lanfani si oriṣiiriṣii eto iranwọ ti ijọba n ṣe fawọn araalu, eyi ti ọpọ eeyan ko lanfani si tẹlẹ.
Eleyi to tun dabi rẹ ni pe ajọ NIMC ko ni beṣu bẹgba lati daabo bo gbogbo nnkan to jẹ aṣiri awọn eeyan eyi ti wọn kọ silẹ lasiko iforukọsilẹ.
Wọnyi ni awọn nnkan to yẹ ki o mọ nipa kaadi idanimọ Naijiria tuntun:
- Kaadi idanimọ tuntun yii yoo maa ṣiṣẹ lori ẹrọ kọmputa ni ibamu pẹlu koodi ICAO ti wọn n lo fun iwe igbeluu.
- Ọjọ ti eeyan ba gba kaadi yii ati nọmba kaadi ọhun yoo wa lori rẹ ni ibamu pẹlu gbedeke ICAO.
- Kaadi yii yoo wulo fun eto ilera, irinajo, ẹyawo, iṣẹ ọgbin, ounjẹ, iranwọ ijọba lori owo ina, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
- Kaadi idanimọ tuntun yii yoo ni nọmba NQR ipe pajawiri lasiko ti ijamba ba ṣẹlẹ.
- Awọn ami idanimọ bi ika ọwọ ati fọto to ti wa lori kọmputa ni yoo wa lori kaadi idanimọ yii.
- Awọn araalu yoo tun lanfani lati le maa lo kaadi naa lawọn agbegbe ti nẹtiwọọki ko ba ti gbewọn to.
- Anfani mii to wa ninu kaadi idanimọ tuntun yii ni pe awọn araalu yoo le maa fi gba owo tabi san owo bii kaadi ATM.
Awọn araalu to ba fẹ gba kaadi yii yoo maa fi orukọ silẹ lori ayelujara, ati lawọn ile ifowopamọ, ati pẹlu awọn aṣoju ajọ NIMC.
Bakan naa ni awọn eeyan tun le fi orukọ silẹ ni ọfiisi ajọ NIMC kaakiri orilẹede Naijiria.