Makinde fi òpópónà Akobo-Olorunda sọrí Gómìnà tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike

Oríṣun àwòrán, others
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lọjọ Ẹti sọri opopona oni ibeji Akobo,Ojurin/Odogbo Barracks Olounda Abaa ni orukọ gomina tẹlẹ nipinlẹ Rivers, Nysome Wike.
Gomina sọ eleyi lasiko to n se ifilọlẹ opopona naa niluu Ibadan.
Oju ọna ni igbagbọ wa pe yoo pari laarin osu mejila, ti yoo si na ijọba ni bilọbu mẹsan ati diẹ ni owo naira.
Makinde ni ida ọgbọn ninu owo oju ọna naa ni ijọba ti san fun agbasẹse naa lati le jara mọ isẹ.
O tun wa fi da awọn ọmọ ipinlẹ Oyo loju pe ijọba oun ko ni dẹkun sise isẹ idagbasoke ti yoo se ọpọlọpọ anafani fun ipinlẹ naa.
“Igbesẹ wa yoo fi aye silẹ fun awọn onisowo lati wa si ipinlẹ Oyo, ti yoo si se anfani fun eto ọrọ aje wa pupọ.”
Makinde ni ọtitọ ni awọn dukia awọn araalu kan yoo lọ si ọna naa sugbọn ijọba ti n pese bi wọn yoo sese iranwọ fun .
O wa rọ awọn araalu, paapa awọn ti agbegbe ọna naa lati gbarukuti ijọba pẹlu igbesẹ naa.
Ọpọlọpọ lori ayelujara ti bu ẹnu atẹlu bi Gomina Makinde se fi orukọ gomina tẹlẹ nipinlẹ Rivers sọri opopona.















