Ìdílé ọba Bilaro Olu-Odo kìlọ̀ lórí ìròyìn tó ní ìjọba Gómìnà Adeleke ti yan Ọmọ Oye tí yóò jẹ Owa Obokun

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/X
Awuyewuye lori ọrọ ta ni yoo jẹ Owa Obokun tuntun tun tu ba ọna mii yọ lẹyin ti idile afọbajẹ Bilaro Olu-Odo niluu Ilesa rọ Gomina Ademola Adeleke ipinlẹ Osun wi pe ko ma dasi ọrọ oye naa.
Bakan naa ni idile afọbajẹ Bilaro Olu-Odo tun rọ awọn ọmọ Ilesa to n ba gomina ipinlẹ Osun ṣiṣẹ wi pe ki wọn ma ṣi gomina lọna lori ati yan Owa Obokun tuntun fun ilẹ Ojesa.
Ninu atẹjade kan eyi akọwe idile Bilaro Olu-Odo, Ọgbẹni Gbenga Tosho Haastrup, buwọlu niluu Osogbo ni o ti ṣalaye pe idile Bilaro Olu-Odo lokan lati jẹ ọba.
Haastrup rọ gbogbo awọn afọbajẹ lati tẹle ilana to wa nlẹ ki wọn si ma ṣegbe lẹyin ẹnikan ninu awọn ọmọ oye to n dupo ọba.
''O ṣe pataki lati sọrọ lori ahesọ kan tawọn eeyan kan n gbe kiri wi pe ijọba ipinlẹ Osun ti yan ọmọ oye ti yoo jẹ Owa Obokun.
A ni igbagbọ pe iroyin ofege lasan ni eyi to si jina si ootọ,'' Haastrup lo sọ bẹẹ.
''Ẹ ma fọrọ oṣelu bọ yiyan Owa Obokun Ilẹ Ijesa''
Idile Bilaro Olu-Odo ni awọn ni igboya ninu Gomina Adeleke lati ṣe ohun to tọ ati ohun to yẹ lori ọrọ naa.
Idile Bilaro Olu-Odo sọ pe ''a gbagbọ ninu gomina wi pe yoo sọ fawọn afọbajẹ lati tẹle ohun ti Ifa ba sọ fun wọn lori ẹni ti yii jẹ Owa Obokun.
Eyi ṣe pataki tori ọrọ oṣleu yatọ si ọba jijẹ.
Nitori naa, a rọ awọn olori ẹgbẹ oṣelu wa papaa julọ Kọmiṣọna fun ijọba ibilẹ ati oye jijẹ lati fawọn oniṣẹṣe laaye lati ṣiṣẹ wọn lai ṣe idiwọ kankan fun wọn.
Ilẹ Ijesa lo ni aṣa ati iṣe, apere Owa kii ṣe ohun ti wọn le maa fi ṣe oṣelu rara.''
Bakan naa ni ẹbi Bilaro Olu-Odo tun rọ awọn afọbajẹ lati ṣe ododo, ki wọn si ma wo bawọn ọmọ oye ṣe lowo lọwọ si.
Idile Bilaro Olu-Odo ko ṣai rọ Gomina Adeleke lẹẹkan si pe ko ma ṣegbe lẹyin ẹnikan to ba fẹ kede Owa Obokun Ilẹ Ijesa tuntun.
Ẹbi Bilaro Olu-Odo ni gbogbo ẹni ti ọrọ yiyan Owa Obokun tuntun ba kan gbọdọ bọwọ fun aṣa iṣẹdalẹ ilẹ Ijesa tori Ifa ni ipilẹ ti ilẹ Ijesa duro le lori.
Ọrọ taa ni yoo jẹ Owa Obokun tuntun da wahala silẹ laarin awọn ọmọ oye
20 Ọ̀pẹ̀̀ 2024
Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Osun ti da Gomina Ademola Adeleke, ati awọn afọbajẹ ilu Ilesa lọwọ kọ lati yan Owa Obokun tuntun fun ilẹ Ijesa.
Ọmọọba Debo Adeyemi ati awọn mẹwaa miran ni wọn pe ẹjọ lorukọ mọlẹbi Ofokutu ti agboole Bilaro Oluodo.
Awọn ti wọn pe lẹjọ ni Gomina Ademola Adeleke; Obanla ilu Ijesa, Oloye Folorunso Adeniyi, ati awọn afọbajẹ mọkanla; igbimọ ọba alaye nilẹ Ijesa; Kọmiṣanna feto idajọ, to fi mọ Kọmiṣanna fọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ.
Eyi waye lẹyin ti Owa Obokun tẹlẹ, Oba Adekunle Aromolaran papoda lọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 Ọjọ kejila, lẹni ọdun mẹrindinlaadọrun un.
Awọn olufẹsunkan naa n rọ ile-ẹjọ lati da Adeleke, awọn aṣoju rẹ, to fi mọ awọn afọbajẹ ilẹ Ijesa lọwọ kọ lati yan Haastrup tabi ẹnikẹni gẹgẹ bi Owa Obokun tilẹ Ijesa titi digba ti ile-ẹjọ yoo fi gbe idajọ kalẹ lori ipo naa.
Onidajọ A. Aderibigbe, lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024 ti wa a paṣẹ pe ki awọn olujẹjọ to wa ninu iwe ẹsun naa dawọ duro lati yan ọba tuntun fun ipo Owa Obokun.
Bakan naa lo tun igbẹjọ siwaju si ọjọ kẹrinla, oṣu kinni, ọdun 2025.
Ohun to yẹ ki o mọ nipa ipo Owa Obokun
Ọkan pataki lara awọn ilu to wa nipinle Osun ni ilu Ilesa, to wa lara awọn ilu to wa ni ilẹ Ijẹṣa. Pupọ awọn ilu naa lo je pe wọn n pe orukọ Ijesa mọ wọn lara. Lara wọn si ni: Erin-Ijesa, Ijeda-Ijesa, Ipetu-Jesa, Ijebu-Jesa, Ipole-Ijesa, Ifewara-Ijesa, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ilu Ileṣa si lo jẹ olu-ilu fun gbogbo awọn ilu miran to wa nilẹ Ijẹṣa.
Gẹgẹ bi awọn akọsilẹ kan ṣe sọ, ọdun 1300 ni wọn da ilẹ Ijesa silẹ. Ajibogun Ajaka Owa Obokun Onida Raharaha to jẹ jagunjagun alagbara, ẹni to jẹ ọmọ-ọmọ Oduwuwa lo da ilu Ijesa silẹ, ṣugbọn Owulase to jẹ ọmọ-ọmọ Ajibogun Ajaka lo fi orukọ Ilesa lelẹ.
Eyi lo fi jẹ pe bi wọn ṣe n pe ilu naa ni Ijesa naa ni wọn tun n pe e ni Ilesa labẹ akọsilẹ ofin.
Ajibogun Ajaka jẹ Owa Obokun Adimula laarin ọdun 1150 si ọdun 1255; Awoka Okile lo jẹ lẹyin rẹ laarin ọdun 1260 si ọdun 1358. Obarabara Olokun Ẹṣin jẹ lọdun 1360 si ọdun 1459.















