Ibùdó ifọpo Warri ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ̀ padà - NNPCL

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkan lara awọn ibudo ifọporọbi to jẹ ti ijọba Naijiria, Warri Refinery, eyi to wa nipinlẹ Delta, ti bẹrẹ iṣẹ lẹyin to ti dẹnukọlẹ fun ọpọlọpọ ọdun.

Ọjọ Aje ni Ọga Agba fun ileeṣẹ naa, Mele Kyari, to kede eyi lasiko to ṣe abẹwo si ibudo naa to ni agbara lati maa pese 125,000 agba epo lojumọ.

Kyari ni lootọ ni ibudo naa ti bẹrẹ iṣẹ, amọ ko tii le ṣiṣẹ ni ida ọgọrun un bayii, nitori pe iṣẹ atunsẹ ṣi n lọ lọwọ.

O ṣalaye pe ẹka mẹta lo wa ni ibudo ifọpo Warri, amọ ẹka kan ti wọn n pe ni Area 1, lo ti bẹrẹ iṣẹ.

Area 1 yii yoo ni agbara lati maa pese Disu, Kerosini, eroja naphtha ati awọn nnkan miran.

Mele Kyari sọ pe wọn o le maa ko awọn nnkan wọnyii lọ silẹ okeere ni ipele yii.

Aarẹ Bola Tinubu ti fi iduunu rẹ han si bi ibudo ifọpo rọbi to wa ni Warri, ipinlẹ Delta, ṣe bẹrẹ si i ṣiṣẹ pada.

Ida ọgọta (60%) ti i ṣe 125, 000bpd agba epo ni wọn ni ibudo naa fi bẹrẹ iṣẹ bayii.

Ọjọ Aje, ọgbọnjọ oṣu Kejila, ọdun 2024 ni aarẹ kede ọrọ naa ninu atẹjade kan.

O ṣalaye pe ohun iwuri to mu inu oun dun, to si dara lati fi ka ẹsẹ 2024 nilẹ ni ibudo ifọpo naa.

Aarẹ Tinubu sọ pe bi ibudo ifọpo to bẹrẹ iṣẹ yii yoo tun fi ọkan awọn ọmọ Naijiria balẹ, pe gbogbo ohun to le lasiko yii yoo pada di ẹrọ.

O ni ileri ọtun tijọba oun ṣe lo ti n wa si imuṣẹ yii, pẹlu bi ibudo ifọpo ti Porthacourt naa ṣe ti gberasọ.

O dupẹ lọwọ ileeṣẹ NNPCL ati Mele Kyari to ni wọn n tẹle aṣẹ oun lati jẹ ki awọn ibudo ifọpo mẹrin to wa ni Naijiria bẹrẹ iṣẹ pada.

Bẹẹ lo rọ wọn pe ki wọn mura si iṣẹ naa, ki ti Kaduna naa le bẹrẹ iṣẹ laipẹ.

'Ó ṣeé ṣe kí owó epo wálẹ̀ sí i pẹ̀lú ibùdó ifọpo yìí'

Awọn alagbata epo ti sọ pe o ṣee ṣe ki owo epo ja walẹ si i pẹlu ibudo ifọpo Warri to bẹrẹ iṣẹ naa.

Awọn alagbata labẹ orukọ 'Nigerian Midstream and Downstream Petroleum Regulatory Authority', ṣalaye pe ifigagbaga ati orogun owo yoo bẹrẹ laarin awọn elepo bayii.

Wọn fi kun un pe yoo di dandan fun wọn lati din owo epo ku, nigba ti wọn ba ti n fọ ọ lorilẹede wa.

Bakan naa ni ileeṣẹ NNPCL fi erongba rẹ han lati maa ta epo ti wọn fọ lorilẹede yii lọ si ilẹ okere, ni paṣipaarọ owo wọn.