Kí ló ń fa àṣìṣe lórí ètò ẹ̀yáwó akẹ́kọ̀ọ́, táwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde fi ń rí ẹ̀yáwó náà gba?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn èèyàn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìjọba àpapọ̀ ti ń kọminú lórí bí ẹ̀yáwó láti fi san owó ilé ẹ̀kọ́ wọn, tí ìjọba àpapọ̀ gbékalẹ̀ ṣe ń wáyé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù ti wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́jáde.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní lẹ́yìn tí àwọn ti parí ètò ẹ̀kọ́ àwọn ni àjọ tó ń rí sí ẹ̀yáwó fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, Nigeria Education Loan Fund, NELFUND ṣẹ̀ṣẹ̀ ń san owó fáwọn ilé ẹ̀kọ́ àwọn.
Nínú àtẹ̀jáde iléeṣẹ́ ìròyìn The PUNCH tí wọ́n gbé jáde lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Karùn-ún, ọdún 2025 sọ pé àwọn èèyàn tọ́rọ̀ náà kàn ní ìjọba tún san owó ẹgbẹ̀rún ogún náírà fáwọn kódà bó ṣe jẹ́ pé àwọn kìí ṣe akẹ́kọ̀ọ́ mọ́.
Àwọn èèyàn náà sọ pé àwọn bèèrè fún ẹ̀yáwó nígbà tí àwọn jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kí àwọn tó parí ètò ẹ̀kọ́ àwọn àmọ́ tí owó náà kò wọlé, táwọn sì ló wá owó lọ́nà mìíràn láti fi san owó náà.
Wọ́n ní ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn nígbà tí àwọn padà gbọ́ pé NELFUND sọ owó náà fún ilé ẹ̀kọ́ àwọn lẹ́yìn tí àwọn kúrò nílé ẹ̀kọ́, táwọn sì ti yanjú owó náà lọ́wọ́ ara à àwọn.
Láti ìgbà tí àjọ tó ń rí sí ìlanilọ́yẹ̀ ní Nàìjíríà ìyẹn National Orientation Agency, NOA fẹ̀sùn kàn pé àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan ń yọ owó lọ́nà àìtọ́ láti ara ẹ̀yáwó tí ìjọba ń pèsè fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.
Bákan náà ni àjọ tó ń gbógunti ìwà ọ̀daràn, Independent Corrupt Practices and Other Related Offences, ICPC ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí àwọn ẹ̀sùn pé àwọn ìwà kò tọ́ kan ń wáyé lórí ètò ẹ̀yáwó náà.
NOA fẹ̀sùn kàn pé àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn ilé ìfowópamọ́ ń mọ̀ọ́mọ̀ láti dá fífún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ẹ̀yáwó náà dúró lọ́nà àti ṣètò owó náà kúmọkùmọ.
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn táwọn iléeṣẹ́ ìròyìn kan ń sọ pé àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan ń yọ owó tó tó N3,500 sí N30,000 látara ẹ̀yáwó ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n san náà.
ICPC nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde sọ pé ìwádìí táwọn ṣe fi hàn pé NELFUND gbé ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù náírà (N100bn) jáde fún ẹ̀yáwó náà àmọ́ tó jẹ́ pé N28.8bn ló dé ọwọ́ àwọn tó bèèrè fún-un.
Agbẹnusọ ICPC, Demola Bakare fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìgbìmọ̀ tó ń rí sí àkànṣe iṣẹ́ ní ICPC ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kété tí àwọn ti gbọ́ nípa àwọn ẹ̀sùn ọ̀hún.
Ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà, NANS ní àwọn máa ṣe ìwọ́de láti fi ìfẹ̀hónú àwọn hàn lórí àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tó ń wáyé lórí pínpín ẹ̀yáwó náà.
'Mi ò rí ẹ̀yáwó NELFUND nígbà tí mo nílò rẹ̀, mi ò ní da owó ti wọ́n san fún ilé ẹ̀kọ́ padà'
Akẹ́kọ̀ọ́ kan sọ pé òun bèèrè fún ẹ̀yáwó lọ́wọ́ NELFUND nígbà tí àwọn nílò owó láti fi san owó ilé ẹ̀kọ́ àmọ́ kò rí owó náà títí tí àsìkò fi tó láti fi san owó ilé ẹ̀kọ́ táwọn sì lọ wá owó lọ́nà mìíràn láti san owó náà.
Ó ní ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún òun pé NELFUND san owó ilé ẹ̀kọ́ náà lẹ́yìn tí òun ti jáde tán.
Ó ṣàlàyé pé nígbà tí òun kàn sí NELFUND láti fi ẹ̀hónú òun hàn lórí owó náà, NELFUND ní kí òun lọ bèèrè owó òun padà lọ́wọ́ ilé ẹ̀kọ́ òun àmọ́ òun kò mọ bí òun ṣe máa ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí òun kìí ṣe akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà mọ́.
Ó fi kun pé wọ́n tún ń san ẹgbẹ̀rún ogún náírà sí òun láti máa ṣàmúlò ní oṣooṣù tó sì jẹ́ pé ìyẹn nìkan ni òun máa dá padà nígbà tí àsìkò bá tó láti dá owó náà padà.
Ẹlòmíràn tó parí ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Benin sọ pé nígbà tí òun wà ní ipele tó kẹ́yìn ni òun bèèrè fún ẹ̀yàwó náà àmọ́ tí òun kò ri tóun fi parí.
Ó ní bí NELFUND ṣe ń ṣètò náà kò dára tó àti pé ó túmọ̀ sí pé wọn kò kajú òṣùwọ̀n pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.
Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga, Academic Staff Union of Universities, ASUU sọ pé àwọn ń wòye sí gbogbo ìwádìí tó ń wáyé lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀yáwó náà àti pé àwọn ń dúró de àbọ̀ ìwádìí ICPC.
ASUU ní gbogbo àwọn tó bá lọ́wọ́ nínú ìwà kò tọ́ tó bá wáyé lórí owó náà ni wọn yóò fojú winá òfin.















