You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
O lé ní èèyàn 100 tí ìbúgbàmù ṣekúpa ní Iran
O le ni ọgọrun eeyan to ti padanu ẹmi wọn lasiko ti ado oloro meji bu gbamu ni ẹgbẹ saare Ọgagun Iran tẹlẹri, to ti di oloogbe, Qasem Soleimani nibi ayẹyẹ ọdun kẹrin ti orilẹede US sekupa ni Iraq.
Ileeṣẹ iroyin Iran, Irib salaye pe ọgunlọgọ eeyan lo tun farapa yanayana nigba ti bu gbamu naa waye ni guusu Kerman.
Irib ka bi igbakeji Gomina Kerman bi o se n sọ pe awọn agbebọn ti kọlu wọn.
Ọpọ fọnran safihan oku awọn eeyan ni oju titi, ti ọkọ pajawiri si n suure lọ ba wọn fun itọju.
A ko ti le sọ ohun to fa ibu gbamu naa, ti kosi si aridaju pe awọn ikọ kan lo wa nidi ibu gbamu naa.
Sugbọn awọn ẹgbẹ Arab ati awọn ikọ Sunni ti ni awọn ni awọn wa nidi awọn ikọlu si awọn ẹsọ alabo ati awọn ẹlẹsin Shia lorilẹede naa ni bi ọdun diẹ sẹyin.
Soleimani yii ni ọpọ ri gẹgẹ bi ọkan lara awọn alagbara lẹyin adari wọn. Ayatollah Ali Khamenei, ko to di pe wọn sekupa ni Iraq ni ọdun 2020.