Ìró ìbọn dún lákọlákọ níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí, ẹ̀mí ogún èèyàn sọnù

O kere tan, ogun eeyan lo ti jade laye, nigba ti awọn mii farapa nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ‘sweet 16’ kan niluu Alabama, nilẹ Amẹrika.

Ileeṣẹ iroyin WRBL jabọ pe afẹmọju ọjọ Aiku lawọn ọlopaa peju sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba Alabama ko tii kede ni pato iye eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ, awọn ileeṣe iroyin abẹle atawọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn sọ pe ọpọ eeyan lo farapa nibẹ.

Iroyin ni ọjọ ori awọn to pọ ju ninu awọn ti iṣelẹ ọhun kan ko ju ọdun mejidinlogun lọ.

WRBL jabọ pe iwadii fi han pe ede aiyede kan to bẹ silẹ nibi ayẹyẹ naa lo jẹ ki awọn kan ṣina ibọn bolẹ ni nnkan bii aago mẹwaa abọ alẹ.

Wọn ti wa ko awọn to farapa lọ sile iwosan fun itọju bayii.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti eeyan kan yoo dede ṣina ibọn fun awọn eeyan l’Amẹrika.

Ilu Amẹrika, ti nnkan bii ọọdunrun ati ọgbọn miliọnu eeyan n gbe lo ni ibọn ti iye rẹ to irinwo miliọnu, eyii to mu ki irufẹ iṣẹlẹ bayii maa waye lemọlemọ.

Lọjọ kan naa ti iṣẹlẹ yii waye ni awọn ọlọpaa sọ pe eeyan meji mii jade laye, nigba ti awọn mẹrin farapa nibi ti ẹnikan ti ṣina ibọn bolẹ niluu Louisville, to wa ni Kentucky.

Ilu Louisville, ni Kentucky yii kan naa ni agbebọn kan ti gbẹmi eeyan marun un nile ifowopamọ kan lọjọ Aje to kọja.