Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kan sáárá sí Owolabi Ajasa fún ṣíṣe àfihàn ọlọ́pàá lọ́nà tó dára

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Muyiwa Adejobi ti kan sara si gbajugbaja osere tiata, Owolabi Ajasa, ẹni to jẹ gomina fun awọn osere tiata nipinlẹ Ogun fun siṣe afihan ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni ọna to dara ju awọn yooku lọ.

Adejobi ni ọpọ igba ni Ajasa ti se ere to ti jẹ ọlọpaa gidi, to si sọ ara rẹ di asoju ileeṣẹ ọlọpaa ni ọna to dara .

Ninu ọrọ to gbe sori ayelujara ni Adejobi ti rọ igboriyin fun agba osere naa, to si rọ awọn yooku lati wo o gẹgẹ awukọse.

“A n fi asiko kan sara si akitiyan Owolabi Ajasa, Gomina fun ẹgbẹ TAMPAM nipinlẹ Ogun, ẹni ti mo ma pe ni ‘Area Commander’ fun bi o o sese afihan ọlọpaa lọna to dara.

“Mo ti n ba Ajasa ati awọn osere miiran sọrọ fun ọdun mẹdogun gẹgẹ bi asoju rere ileeṣẹ ọlọpaa. Owolabi da yatọ ninu wọn nitori o mọ nnkan to se pẹlu awọn ere sinima rẹ to ti se ọlọpaa. Mo le sọ loni pe asoju ọlọpaa rere ni Owolabi.

“Mo rọ awọn yooku lati wo awukọse rẹ , ti wọn si se ohun to tọ labẹ ofin ti wọn ba ti n wọ asọ ọlọpaa ninu ere sinima wọn, eyi ti ko ni fa ija laarinh ileeṣẹ ọlọpaa ati awujọ awọn osere tiata paajulọ awọn adẹrinposọnu. A ri lati sisẹ pọ fun ilọsiwaju ileeṣẹ mejeeje lorilẹede Naijiria.

“A dupẹ, Owolabi Ajasa, Mo kan sara si rẹ pupọ.”