You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ta ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka tí Ààrẹ Tinubu fi orúkọ rẹ̀ sọ gbọ̀ngàn àṣà orílẹ́èdè Nàìjíríà tó wà l’Eko?
Ni ọjọ kejila oṣu Keje ọdun 2024 yii ni Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu, fi orukọ ogbontagi onkọwe n ni, Ọjọgbọn Wole Soyinka sọ gbọngan aṣa Naijiria to wa niluu Eko.
Ọpọ eeyan lo ti lu aarẹ Tinubu lọgọ ẹnu fun imọyi yii ti o ṣe fun agbaọjẹ onkọwe naa.
Ọjọgbọn Soyinka to ti pe ẹni aadọrun un ọdun loke eepẹ bayii ni ọpọ ti n sọ nipa rẹ lori itakun ayelujara lẹyin igbesẹ ijọba apapọ lati fi orukọ rẹ sọ gbagede aṣa to wa niluu Eko.
Wo awọn nnkan to yẹ ki o mọ nipa Ọjọgbọn Wole Soyinka
A bi Akinwande Oluwole Babatunde Soyinka lọjọ kẹtala oṣu Keje ọdun 1934 niluu Abeokuta ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ogun lonii.
Soyinka bẹrẹ ile iwe lẹyin to ti lọ sile ẹkọ, o tẹsiwaju ẹkọ rẹ ni ilẹ ẹkọ giga ti ijọba to wa niluu Ibadan lọdun 1954.
Soyinka tesiwaju lẹnu ẹkọ rẹ ni ile ẹkọ giga Fasiti Leeds nilẹ Gẹẹsi nibi to ti kẹkọọ gboye ninu ede oyinbo lọdun 1957.
Ni fasiti yii kan naa ni Soyinka ti kẹkọọ gboye kẹta ni fasiti ti o ṣi di Ọmọwe.
Soyinka fi ifẹ han si ere siṣe gan an laarin ọdun mẹfa to lo nilẹ Gẹẹsi nigba to n kẹkọọ nibẹ.
Lai fọta pe, Soyinka kọ ere ti akọle rẹ n jẹ The Swanp Dwellers lọdun 1958 eyi to gbe jade niluu London.
Eyi ibẹrẹ irinajo si ọna ti yoo fi di ilumọọka onkọwe kaakiri gbogbo agbaye.
Lọdun 1960 ti orilẹede Naijiria gbominira ni Soyinka ri owo iranwọ Rockefeller gba, eyi to fi wa kẹkọọ nigba ere ori itage ilẹ adulawọ ni Naijiria.
Lati ọdun 1975 ni Soyinka ti di Ọjọgbọn ninu Litiresọ, o ṣi ti ṣiṣẹ olukọ ni fasiti UI n’Ibadan, fasiti OAU ni Ile-Ife ati fasiti UNILAG niluu Eko bakan naa.
Soyinka da ẹgbẹ tiata silẹ
Lọdun 1960 ti orilẹede Naijiria gba ominira ni Soyinka ṣe ifilọlẹ ẹgbẹ theatre rẹ eleyii to pe orukọ rẹ ni ‘’The 1960 Masks.’’
O ṣi tun da ẹgbẹ tiata mii ẹyi to pe orukọ rẹ ni ‘’Orisun Theatre Comapany’’ silẹ.
Bayii ni Soyinka bẹrẹ si ni maa kopa ninu oriṣiiriṣii ere ti awọn mii naa ṣi tun n pe e lati kopa ninu ere wọn.
Ọjọgbọn Soyinka tun maa n kọ awọn akẹkọọ ni fasiti Cambridge, Sheffield ati fasiti Yale.
Lẹyin ere The Swanp Dwellers ti o gbe jade lọdun 1958, Soyinka tun gbe ere The Lion and Jewel jade lọdun 1959.
Loṣu Kọkanla ọdun 1959 kan naa ni o ti gbe ere ‘’An Evening without Décor,” jade eyi ti oun fun ra rẹ kopa ninu ere ọhun.
Loṣu Karun un ọdun 1960 ni Soyinka ṣe Yang Sun ninu ere ‘’The Good Woman of Setzuan.’’
Loṣu Kẹwaa ọdun 1960 ni o tun kopa ninu ere rẹ ti o pe orukọ rẹ ni ‘’A Dance of the Forests.’’
Laarin ọdun 1960 si 1964, Soyinka dari ọpọ ere tawọn olukọtan mii kọ.
Meloo ni a fẹ ka ninu eyin adipele, a fẹ le ma ka iwe ti Soyinka kọ tan.
Ijọba ologun Naijiria ju Soyinka sẹwọn lasiko ogun abẹle Biafra
Ogun abẹlẹ tawọn kan mọ si ogun Biafra bẹ silẹ lọdun 1967 ninu eyi ti ọpọ ẹmi ti ṣofo.
Lasiko yii ni Soyinka kọ iwe apilẹkọ ninu iwe iroyin eyi to fi pe fun didawọ ogun naa duro.
Lẹyin naa ni ijọba ologun labẹ alaṣẹ Yakubu Gowon mu un ti wọn ṣi ju u sẹwọn.
Ijọba ologun fẹsun kan Soyinka wi pe o gbimọ pọ pẹlu awọn ọmogun Biafra to doju ija jọ ijọba Naijiria wi pe awọn fẹ ya kuro lara orilẹede Naijiria.
Ọdun 1969 ni ijọba ologun too tu Soyinka silẹ lẹwọn.
Soyinka gba oye to ga julọ lagbaaye ninu Litiresọ lọdun 1986
Igbimọ Nobel Prize eyun un ni ami idanilọla fun iṣẹ to lamilaaka da Soyinka lọla pẹlu ami ẹyẹ to ga julọ ninu ẹkọ Litiresọ lagbaaye lọdun 1986.
Lorilẹede Sweden ni ayẹyẹ idanilọla naa ti waye lọdun 1986.
Soyinka ko ju ẹni aadọta ọdun le diẹ lọ nigba to fi gba ami ẹyẹ yii.
Koda, oun ni ẹni akọkọ lati ilẹ Adulawọ ti yoo kọkọ gba iru ami ẹyẹ yii.
Ami ẹyẹ yii lo jẹ ki Soyinka di ilumọọka kaakiri agbaye ninu awọn onkọtan Litiresọ.
Ọpọ ere ti Soyinka kọ lo ni ṣe pẹlu aṣa ati iṣe ẹya Yoruba.