You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èèyàn mẹ́wàá, ọkọ̀ mẹ́ta jóná bí ọkọ̀ agbépo ṣe gbiná lọ́nà mọ́rosẹ̀ Eko sì Ibadan
- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Isẹlẹ ibanujẹ lo waye lowurọ Ọjọbọ nigba ti tanka ọkọ agbepo kan gbina ni opopona mọrosẹ Eko si Ibadan.
Eeyan mẹwaa ati ọkọ mẹta si jona kọja aala ni ni ikorita ọna Sagamu, ti isẹlẹ naa ti waye.
Ibugbamu naa lo waye ni dede ago kan oru ni Ogunjọ osu kẹwaa ni agbegbe Araromi lẹyin ile epo Conoil to wa nitosi Sagamu.
Ninu atẹsita ti Agbẹnusọ ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC, Florence Okpe buwọlu, o ni tanka epo meji, bọọsi akero ati ọkọ trailer nla lo kọlu ara wọn loju opopona
O ni awọn nomba idanimọ awọn ọkọ naa ni, AKL198ZT MACK TRUCK, FFE361XB MAZDA BUS amọ ti ko si nọmba idanimọ lara awọn ọkọ meji yoku.
"Awọn awakọ to n sare asapajude lo lọ kọlu tanka epo ti ina fi sọ"
Okpe ni nkan to sokunfa ijamba naa ni ere asapajude ti awọn awakọ naa guule, ti wọn ko si le dari ọkọ naa nigba ti wọn de ibi kan loju opopona naa.
O ni eyi lo mu ki wọn kọlu ọkọ tanka epo to fa iṣẹlẹ naa.
O tẹsiwaju pe awọn ti gbe awọn oku naa lọ si ile wosan ile ẹkọ fasiti Olabisi Onabanjo to wa niluu Sagamu.
Wọn si ti gbe awọn ọkọ naa kuro loju opopona lati dena sunkẹrẹ fakẹrẹ ọpọ fun awọn arinrinajo.
Ahmed Umar, to n dari ajọ to n se akoso eto irinna loju popo ni ipinlẹ Ogun wa ti ransẹ ibanikẹdun sawọn mọlẹbi awọn ti ijamba naa ba lasiko to ṣe abẹwọ sibi isẹlẹ na.
O wa rọ awọn awakọ lati dẹkun sisa ere asapajude ti wón ba ti n ri irinajo wọn.
Ọkọ̀ òfurufú ológun Russia já lulẹ̀, èèyàn 13 kú
Kò dín ní ènìyàn mẹ́tàlá tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní orílẹ̀ èdè Russia, bí ọkọ̀ òfurufú ọmọ ogun kan ṣe já lulẹ̀ lé ilé ìgbé kan lórí.
Àwọn aláṣẹ Russia ní agbègbè Yeysk ní gúúsù Ruusia ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
Ní ọjọ́ ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù Kẹwàá ni ọkọ òfurufú náà já lulẹ̀.
Ènìyàn 68 ni wọ́n yọ nínú ilé alájà mẹ́sàn-án tó gbiná torí bàálù tó já le lórí
Àwọn awakọ̀ òfurufú méjì tó wà nínú ọkọ̀ òfurufú Su-34 ọ̀hún ni ìròyìn ní wọ́n mórí bọ́, kí ọkọ̀ náà tó já lé ilé náà lórí.
Bí ọkọ òfurufú náà ṣe já lé ilé náà lórí ni iná ńlá sọ nínú ilé ọ̀hún, tó sì ṣokùnfà ikú ènìyàn mẹ́tàlá ó kéré tán.
Àwọn tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní orílẹ̀ èdè Russia, lẹ́yìn tí wọ́n parí ètò láti dóòlà àwọn tó há sínú ilé náà, sọ pe ọmọdé mẹ́ta ló wà lára àwọn tó jẹ́ Ọlọ́run nípè.
Àwọn aláṣẹ ní ènìyàn méjìdínláàdọ́rin ni wọ́n yọ nínú ilé alájà mẹ́sàn-án tó gbaná náà.
Bákan náà ni wọ́n ní ènìyàn mọ́kàndínlógún ló ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn.
Iléeṣẹ́ ọmọ ogun Russia ní àwọn awakọ̀ òfurufú náà ní iná kan tó ṣẹ́yọ lára éńgíìnì ọkọ̀ náà, ló fà á tó fi ja lulẹ̀.
lu ti baalu ti ja ni Russia ti n ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fawọn ọmọ ogun orí omi rẹ̀
Fídíò kan ree níbí tí àwọn ará ìlú ṣe ń gbìyànjú láti ran ọ̀kan lára àwọn awakọ̀ òfurufú náà lọ́wọ́ níbi tó ṣubú lulẹ̀ sí.
Ìlú Yeysk ló pààlà pẹ̀lú odò Azov ní Mariupol, ìlà oòrùn Ukraine níbi tí ogun tí Russia àti Ukraine ti ń wáyé.
Ibẹ̀ ni Russia ń lò láti fi ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọmọ ogun orí omi rẹ̀.
Ìjọba ti dárí àwọn aláṣẹ láti tètè pèsè ohun ìrànwọ́ fún àwọn tó lùgbàdì ìṣẹ̀lẹ̀ iná náà nínú ilé méjì tí ọkọ̀ òfurufú náà já lé.
Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ ní Russia ní àwọn tí bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìjàm̀bá náà.