You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Òkú sùn bí jàǹdùkú ṣe kọlu ìpolongo Atiku, PDP àti APC tahùn síra wọn
Rogbodiyan bẹ silẹ lọjọ Aje lasiko ti awọn janduku kan ya bo gbagede ti ẹgbẹ oṣelu PDP ti n ṣe ipolongo ibo niluu Kaduna, ti wọn si kọlu awọn ero to peju sibẹ.
Awọn janduku naa yabo papa iṣere Ranches Bees ti eto naa ti waye pẹlu oniruru ohun ija lọwọ wọn bii igi, ada atawọn ohun mii lati lati kọlu awọn to wa nibẹ.
Igba mẹta ọtọọtọ lawọn janduku naa kọlu papa iṣẹre ọhun, ko to di pe awọn ẹsọ alaabo ri aye lati le wọn jade.
Atiku sọrọ lori ikọlu naa
Ẹ fẹ pa PDP lẹnumọ lati maṣe ipolongo ibo lẹ fi pa eeyan nibi ipolongo wa - Atiku
Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣẹlu naa, Atiku Abubakar ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu ọhun.
Gẹgẹ bii ohun ti Atiku sọ loju opo Twitter rẹ, ikọlu to waye ni Kaduna ati Zamfara, eyii to yọri si iku ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kan, jẹ ọna lati pa ẹgbẹ naa lẹnumọ ko ma le ṣe ipolongo ibo lawọn ipinlẹ naa ni.
O ni “Mo ti gbọ nipa ikọlu ti awọn ọmọ ita ṣe si awọn ọmọ ẹgbẹ wa ni ipinlẹ Zamfara, eyii to mu ẹmi ọmọ ẹgbẹ kan lọ.
“Mi o faramọ ikọlu naa rara nitori o jẹ igbiyanju lati tẹ ẹtọ awọn ọmọ Naijiria lati korajọ labẹ ofin mọlẹ ni, o tun jẹ ọna kan gboogi lati di wa lọna ipolongo ibo Aarẹ.”
“Mo fẹ ko da awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ni Zamfara loju pe mo wa lẹyin wọn bii ike, mo si ba awọn mọlẹbi atawọn ọrẹ awọn to ṣeṣe ninu ikọlu to waye nibẹ kẹdun.”
Ẹru Atiku lo n ba APC bi araalu ṣe tẹwọgba a - PDP
Ẹwẹ, ninu atẹjade kan ti Debo Ologunagba, to jẹ agbẹnusọ PDP fi lede, o ni ẹgbẹ oṣelu APC lo wa nidi ikọlu naa.
Ologunagba ni “Ikọlu ti wọn ṣe si awọn ọmọ Naijiria ati eyii ti wọn ṣe ikọ ipolongo ibo Aarẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ko ṣẹyin oludje sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Kaduna.
“A mọ pe pe ẹru Atiku n ba APC bi awọn araalu ṣe tẹwọgbaa nitori o dantọ lati tu Naijiria ṣe.
Ologunagba sọ pe ẹru ko b’odo ẹgbẹ awọn nitori ireti ti awọn araalu ni ninu oludije wọn.
Lẹyin naa lo ke si Aarẹ Muhammadu Buhari lati fa awọn awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ leti ki wọn dẹkun ati maa da ilu ru, ki wọn si faye gba eto idibo ti ko ni ẹja n bakan ninu lọdun 2023.
A ko mọ ẹni to da eto ipolongo ẹgbẹ wọn ru - APC fesi
Ninu ọrọ tirẹ, akọwe ẹgbẹ oṣelu APC ni Kaduna, Yahaya Baba-Pate sọ pe ẹgbẹ oṣelu awọn kii ṣe ẹgbẹ oni jagidijagan.
O ni “Ẹgbẹ onirẹlẹ ni ẹgbẹ wa... a ko mọ ẹni to da eto ipolongo ẹgbẹ wọn ru.”
“A ti ṣe ojuṣe wa lati ri daju pe awọn oludibo ni Kaduna yoo to ṣeyin wa lọjọ dbibo, nitori naa a ko nilo lati bẹ awọn janduku lọwẹ ki a to jawe olubori ninu eto idibo kankan.”