Bàbá onílé tó fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́sàn-àn lòpọ̀ gba ẹ̀wọ̀n gbére

Ìgbà mẹ́rin ni Bàbá Lárìnlọdù bá mi lòpọ̀ kí ẹ̀gbọ́n mi tó rí wa - Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án

Ile ẹjọ giga kan nipinlẹ Ekiti, ti ju arakunrin kan, ẹni ọdún mejilelọgọta, Daudu Jimoh, si ẹwọn gbere fun fifi ipa ba ọmọde ni ibalopọ. Wọn fi ẹ̀sùn kan Ọgbẹni Jimoh, pe o fi ipa ba ọmọdebinrin naa lopọ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2029, nile rẹ to wa n'ilu Ilupeju-Ekiti. Iwa naa ni ile ẹjọ sọ pe o tako abala kọkandinlọgbọn ofin to wa fun ẹtọ awọn ọmọde nipinlẹ Ekiti. Nigba to n jẹri nile ẹjọ, ọmọdebinrin naa sọ pe Ọgbẹni Jimoh, ti wọn tun n pe ni Baba Cooler, jẹ larinlọọdu awọn. O ni igba mẹrin lo ti ba oun ni ibalopọ, ko to di pe ẹ̀gbọ́n oun obinrin ká wọn ni ọjọ naa. Ọmọdebinrin naa sọ pe o ti kilọ fun oun lati máse sọ fun ẹnikẹ́ni, bibẹẹkọ, oun yoo kú. O ni ẹgbọn oun lo sọ gbogbo nkan to sẹlẹ fun iya awọn. Yatọ si ọrọ ẹnu ọmọ naa, ẹlẹrii mẹrin lo tun jẹri tako Jimoh, ti wọn si tun fi esi ayẹwo ti ileewosan ṣe fun ọmọ naa han.

Sugbọn ninu ọrọ rẹ, ọdaran naa nipasẹ agbẹjọro rẹ sọ pe lootọ ni oun gbiyanju rẹ, amọ oun ko ni ibalopọ pẹlu ọmọ naa.