Àjọṣepọ̀ wo ló wà láàárín àṣeyọrí Trump àti àyípadà ojú ọjọ́?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Jeremy Howell
- Role, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Nibi apejọ awọn orilẹede lori ọrọ oju ọjọ, eti ti wọn pe ni COP to n lọwọ ni Azerbaijan, awọn amoye nipa oju ọjọ lati ọpọ orilẹede yoo jiroro lori awọn igbese tuntun lati gbiyanju wọn mu lati adinku awọn itujade afẹfẹ to n ṣe akoba si oju ofurufu, carbon emission.
Ireti wa pe awọn adikun yoo de ba ooru ni awọn ọdun to n bọ, to tu mọ pe gbogbo agbaye ni yoo ti waye.
Ẹwẹ, Donald Trump ni ireti wa pe yoo yọ Amẹrika kuro ninu awọn igbimọ agbaye to n risi ayipada oju ọjọ ni kete to ba di Aarẹ, gẹgẹ bi o se se lasiko saa akọkọ rẹ.
Ki ni afojusun ayipada oju ọjọ agbaye?
Ni ipade COP21 ni Ilu Paris ni ọdun 2015, o fẹrẹ to awọn orilẹ-ede 200 to ṣe adehun lati gbiyanju lati mu adikun ooru ni, ki o si ma ju 1.5C lọ.
Eyi lo wa lati le yago fun awọn ipa to ṣe pataki ti iyipada oju-ọjọ le se bi sisekupa irugbin ati omiyale.
Ajo Agbaye UN sọ pe lati ṣe iranlọwọ lati jẹ ki imorusi agbaye wa laarin 1.5C, awọn orilẹ-ede nilo lati dẹkun fifi carbon dioxide (CO2) ati methane sinu agbegbe, nitori wọn fa ooru.

Afojusun wọn ni lati da emissions si idaji ni ọdun 2030, ti ko si ni si emissions mọ ni ọdun 2050.
Ọpọ awọn orilẹ-ede lo ti n gba ero yii.
Awọn igbese lati ṣaṣeyọri rẹ ni iyipada awọn epo fosaili bii epo, gaasi ati eedu fun ohun agbara isọdọtun bi oorun ati afẹfẹ. Eyi tunọ si piparọ ọkọ to n lo epo si eyi ti o n lo ina mọnamọna.
Ni apejọ COP29 ni Baku, awọn aṣoju orilẹ-ede yoo jiroro siwaju lori igbese apapọ lati ṣe lati ṣaṣeyọri ibi-afẹde ti wọn forukọsilẹ fun ni Ilu Paris.
Igbesẹ wo ni Amẹrika ti gbe?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbesẹ lori ayipada oju-ọjọ jẹ ohun pataki fun Aarẹ Amẹrika to jade Joe Biden.
Ni ọdun 2022 o fowo si ofin Ofin Idinku Inflation (IRA).
Eyi pese opo owo fun fun atunṣe owo ori, iyanlowo fun awọn ileeṣẹ to n pese atẹgun to n alaafia, ti o si pe se awọn iṣẹ to le ni 300,000 ni eka naa.
Ijọba Biden tun ti sọ fun awọn ileeṣẹ to n risi ọrọ agbara lati mu emissions kuro ki ọdun 2040 to de, ti wọn si ma pese awọn ayọkẹlẹ ti ko ni epo lẹyin ọdun 2035.
Bakan naa lo tun seto afojusun ida 55% ina mọnamọna lati wa lati ibẹ ni ọdun 2025, 75% ni 2030 ati 100% ni 2035.
Bawo ni iṣejọba Trump se le mu ayipada ba ilana ayipada oju ọjọ?
Aarẹ ti ilu sẹsẹ dibo yan, Trump jẹ ẹni ti o tako ayipada oju-ọjọ ti ko si gbagbọ ninu rẹ” (ṣugbọn tun ṣe apejuwe rẹ ni aaye miiran bi “koko-ọrọ to ṣe pataki”).
Ni ọdun 2017 ni saa akọkọ rẹ, Ọgbẹni Trump fa Amẹrika kuro ni adehun oju-ọjọ Paris, eyiti o fi gbedeke si awọn gaasi eefin ti Amẹrika le gbejade.
Ẹwẹ, Amẹrikani anfani lati lọ kuro ni adehun ni ọdun 2020 - oṣu diẹ ṣaaju ki Trump to kuro ni ọfiisi - ti Aarẹ Biden darapọ mọ lẹyin ti o di Aare.
Mr Trump ni ireti wa pe yoo tun jade kuro ni Adehun Paris lẹẹkansi, nigbati o ba wọ White House fun igba keji rẹ ni Oṣu Kini ọdun 2025. Ni akoko yii, Amẹrika le jade kuro ninu adehun fun ọdun kan.
Se afẹfẹ gassi green energy yoo parun US?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
MỌpọlọpọ awọn amoye ro pe laibikita ihuwasi Trump si ayipada oju-ọjọ, iyipada si agbara alawọ ewe ni Amẹrika yoo tẹsiwaju.
Ni akọkọ, eyi jẹ nitori ọpọlọpọ awọn oloselu ẹgbẹ rẹ ni Repubican Party fẹran Ofin Idinku owo ori. O nireti lati ṣe ipilẹṣẹ bi $ 3trn ni lilo lori agbara alawọ ewe bii agbara oorun , ati 85% ti inawo titi di isisiyi ti wa ni awọn agbegbe eyiti o dibo Republikani.
Nibayi, ile-iṣẹ agbara isọdọtun ni agbaye ti di iṣowo nla.
Ile White le ni itara fun pupọ ti idoko-owo ti yoo wa si Amẹrika bi o ti ṣee ṣe, dipo awọn abanidije bii China.












