Àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì ṣàwárí igbó tó ti wà fún ọdún tó lé nì mílíọ̀nù mẹ́rin

Aworan Igbo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣebi airin jina, lai ri abuke ọkẹrẹ, awọn onimọ sayẹnsi ti ṣe awari igbo kan ti wọn gbagbọ pe o ti wa fun ọdun to le ni miliọnu mẹrin.

Ni apa iwọ-oorun guusu orilẹede England ni wọn ti ri igbo naa.

Lori oke kan to wa lẹgbẹ Minehead ni Somerset ni wọn ti gan-an ni igbo ọhun.

Awọn oniṣẹ iwadii ni ile ẹkọ giga fasiti Cambridge ati Cardiff fidi rẹ mulẹ pe, awọn igi to wa ninu igbo yii lo dagba julọ lorilẹede UK ati ni gbogbo agbaye.

Bakan naa ni wọn sọ nipa bi awọn igi inu igbo yii ṣe gun to.

Awọn onimọ sayẹnsi ṣapejuwe bi awọn igi yii ṣe mu ilẹ duro ti wọn si pa aala lẹgbẹ omi ni bii ọgọrun ọdun sẹyin.

Aworan ori oke apata

Oríṣun àwòrán, Neil Davies

"Nigba ti mo kọkọ ri aworan awọn igi yii, kete ni mo ti mọ ohun ti wọn fara jọ tori mo ti ṣe iṣẹ iwadii lori irufẹ igi yii fun bii ọgbọn ọdun," Ọmọwe Christopher Berry ti ile ẹkọ gíga fasiti Cardiff ṣalaye.

Ọmọwe Paul Kenrick to jẹ akọṣẹmọṣẹ ni ile itọju nnkan iṣẹmbaye ṣalaye pe ẹri wa pe awọn igi inu igbo naa ti dagba papọ fun igba pipẹ.

Awọn onimọ sayẹnsi naa ni igbo yii ti wa ṣaaju ilu New York eleyii ti wọn ni o ti wa fun bi ọdun miliọnu mẹrin.

Aworan ori oke apata

Oríṣun àwòrán, Chris Berry

Ọjọgbọn Neil Davies ti ẹka ile ẹkọ gíga fasiti Cambridge sọ pe "igbo to rẹwa ni igbo yii, o yatọ si awọn igbo ti a n ri lonii.

Ko si koriko tabi igi ti a ko le sọ nipa rẹ mọ lonii, amọ, awọn igi kan wa ti wọn ni ipa lori awọn kokoro ori ilẹ."

Ọmọwe Kenrick naa sọ pe awọn igi inu igbo yii yatọ gede gede sí awọn igi inu igbo ti a n ri lasiko yii.

Igi Dicksonia jẹ igi kan ti a le ri ni ilẹ olotutuu, bakan naa ni irufẹ igi yii wa ni ilẹ Australia ati Great Britain bakan naa.