You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn nńkan tí o kò lè gbé wọ bààlúù ní Naijiria
Lati igba ti wahala to waye laarin gbjumọ olorin Fuji, Wasiu Ayinde, ati awọn oṣiṣẹ baalu kan niluu Abuja, ni ọpọ eeyan ti n sọ ero ọkan wọn lori iṣẹlẹ naa.
Ohun to kari ayelujara lẹyin fidio to ṣafihan Mayegun ilẹ Yoruba ọhun to fẹẹ di baaluu lọna ni pe ṣe ko mọ pe a ki i ṣe bẹẹ ni.
Bẹẹ ni awọn mii n sọ pe ṣebi ofin to de iwa ti eeyan le hu to ba fẹẹ ba ọkọ ofurufu rin irinajo ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa fi n kọ Wasiu ti ko si gba.
Kaluku n sọ pe ofin to de irinajo baaluu ati awọn ohun ti eeyan le gbe wọbe wa, bẹẹ lofin si wa to de iṣẹ awọn awakọ baaluu naa pẹlu.
Lati ṣalaye ohun ti ofin sọ nipa ohun ti arinrinajo ko le gbe wọ baaluu ni Naijiria yii, eyi ni atupalẹ rẹ gẹgẹ bi ileeṣẹ United Nigeria Airline ati KLM ṣe gbe e kalẹ.
Àwọn ohun tí òfin kò fi ààyè gbà láti gbé wọ ọkọ̀ òfurufú ní Naijiria
Lorilẹede Naijiria, ọpọ nnkan ni ofin ko faaye gba pe ki arinrinajo ofurufu gbe wọ baaluu. Lara wọn ni:
- Ado oloro to le bu gbamu, dynamite, ẹtu ibọn, iṣana igbalode, iyẹn laita ti wọn fi n ṣana, banga ti awọn eeyan maa n yin, eroja ti wọn fi n po ọda ti a mọ si thinner.
- Awọn eroja to le gbina lojiji.
- Ohun to mú bii abẹ ifari, ọbẹ, irin ṣonṣo to le gun eeyan tabi ohunkohun to le da bi nnkan ọṣẹ́.
- Nnkan ija ogun, ibọn ti a mọ si 'stun gun' to le mu ara eeyan sẹ giiri.
- Awọn nnkan olomi to ba ti kọja odiwọn 100ml.
- Kẹmika
- Majele tabi ohunkohun to ba lewu
- Awọn ọja to lodi sofin lati ta.
Labala nnkan bii omi ti Wasiu lufin rẹ yii ni a ti ri awọn àgbá eroja bii oje (Gel).
Nnkan olomi to ba ti tobi ju iwọn ọgọrun miligraamu lọ (100ml), ofin ko faaye gba a lati wọ baaluu.
Ẹranko abẹ̀mí
Aaye ko gba arinrinajo ofurufu ni Naijiria lati ko ẹranko wọ baaluu, afi to ba jẹ ẹranko ti wọn n lo fun idi tabi iṣẹ pataki kan.
Ounjẹ
Awọn ounjẹ to ba le tete bajẹ ti yoo si maa rà bii ewebẹ, eso ati bẹẹ bẹẹ lọ le maa raye ninu baaluu, gẹgẹ bi ofin awọn aṣọbode ṣe sọ.
Owó
Bo tilẹ jẹ pe owo ki i ṣe eewọ lati gbe wọ baaluu, o loju iye owo ti ofin faaye gba.
Owo to ba ti pọ ju debi to mu ifuradani, olowo naa yoo ṣalaye ibi to ti ri i.
Awọn nnkan iṣere to n lo batiri
Lọpọ igba, awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu maa n fi ofin de awọn to maa n ko taya si ẹsẹ ti wọn yoo maa fi ṣe ere idaraya.
Awọn irinṣẹ to n lo batiri ati lithium naa ki i saba jẹ itẹwọgba.
Àkíyèsí pàtàkì
Ohun to jẹ eewọ nileeṣẹ ọkọ ofurufu kan le ma jẹ eewọ nibo mi-in, eyi lo fi ṣe pataki fun arinrinajo lati yẹ ofin ileeṣẹ to fẹẹ ba rin wo ko to o bẹrẹ irinajo ọhun.
Gbogbo ohun ti International Air Transport ka silẹ pe eewọ ni, naa lo jẹ eewọ kaakiri awọn ileeṣẹ ọlọkọ ofurufu gbogbo.
Lakootan, ofin awọn aṣọbode ni papakọ ofurufu lori ohun ti o le gbe rin irinajo ko yi pada.
Ohun ti wọn ba sọ labẹ ge.
Ṣé àwọn àsìkò kan wà tí òfin yóò gba kí èèyàn gbé nǹkan mímu wọ bààlúù?
Bẹẹ ni. Awọn nnkan kan wa labẹ ofin to le faaye gba ki arinrinajo gbe nnkan mimu wọ baaluu.
1. Oogun oyinbo
Akọkọ fun iru asiko bẹẹ ni to ba jẹ pe oogun ti dokita la kalẹ pe ki arinriajo naa maa mu ni.
Awọn oogun bii oogun ikọ, oogun to n ṣe atunṣe ṣuga ninu ẹjẹ, oogun oju ti iwọn rẹ ko kọja alakalẹ ofin.
Arinrinajo naa yoo si ti fi eyi han awọn ẹṣọ oju ọna ko too wọle.
2.Awọn nnkan elo itọju ọmọde
Awọn nnkan bii omi ọyan, ounjẹ ọmọ, eso olomi fun ọmọde to mọ niwọn naa le wọ baalu pẹlu ero ọkọ.
Wọn le ju iwọn 100 ml lọ .
Awọn iyalọmọ naa le gbe omi ọyan dani fun ọmọ wọn ti ko si lori irinajo pẹlu wọn .
Awọn nnkan olomi ti wọn ra ni papakọ ofurufu ti wọn si ti di lọna ti eeyan le fi mọ ohun to wa ninu rẹ, ti iwe ẹri ''mo ra ọja'' naa si wa nibẹ pẹlu.
Awọn nnkan olomi ti wọn n lo fun ilera naa le lọ pẹlu, bi eeyan ba ti mu awọn iwe to ni i ṣe pẹlu rẹ dani.
Ṣugbọn labẹẹ bo ṣe wu ko ri, arinrinajo ko gbọdọ tapa si ofin wọnyii, ko si gbọdọ huwa to tako alaafia irinajo naa, bi eyi to mu Wasiu Ayinde di ẹni ti wọn fofin de pe baaluu kankan ko gbọdọ gbe e rin irinajo lati asiko yii fun oṣu mẹfa gbako.