Àlàyé lórí ohun tó ṣokùnfà ikú gbajúmọ̀ òṣèré sinimá, Cynthia Okereke

Cynthia okereke

Oríṣun àwòrán, Cynthia okereke

Awọn mọlebi gbajumọ elere tiata, Cynthia Okereke to jade laye ti salaye pe aisan lo sekupa a.

Ninu ọrọ ti wọn ba BBC sọ, Mọlẹbi Cynthia Okereke ni fun ọpọlọpọ oṣu lo fi wa l’ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun .

Wọn fi kun un pe awọn ko le sọ ni pato bi ilera rẹ ṣe de ipo yii.

Lara awọn akẹgbẹ rẹ lagbo oṣere n8 wọn kọkọ fọnrere iroyin iku rẹ lọjọru pẹlu oniruru ọrọ idaro.

Aarẹ ẹgbẹ awọn onitiata ede oyinbo ni Naijiria, (Actors Guild of Nigeria), Emeka Rollas sọ fun BBC pe, “ọkọ arabinrin Okereke fi to mi leti pe iporuru ọkan” kun ara ohun to koju oserebirin naa ki o to jade laye.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa Cynthia Okereke

Cynthia okereke

Oríṣun àwòrán, Cynthia okereke

  • Nnkan bi ọgọta ọdun lo lo laye
  • O lọkọ, o bimọ o si tun ní ọmọ-ọmọ
  • Ọmọ bibi ipinlẹ Enugu ni..
  • Lara awọn ere sinima to gbe e si aye ni ni sinima
  • Ọjọ Isẹgun, ọjọ kọkanla oṣu kọkanla oṣu keje ọdun 2023 ni Cynthia jade laye