Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọkọ tó fá ọmọ odó yọ láti ṣekúpa ìyàwó rẹ̀

Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Bauchi sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji kan to gbiyanju lati ṣekupa iyawo rẹ pẹlu ọmọ odo.

Gẹgẹ bii ileeṣẹ Ọlọpaa ṣe sọ, ọkunrin naa gbiyanju lati ṣekupa iyawo rẹ ki o baa le ta ẹrọ amohunmaworan wọn ko si lo owo naa fi tun sọọbu rẹ ṣe.

Eyi lo wa ninu atẹjade ti Alukoro fun ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Bauchi, Ahmed Wakil gbe jade fun awọn akọroyin.

Wakil ni ọkọ naa jẹwọ lasiko iwadii pe oun pariwo sita pe ole ja ile oun.

"Lọjọ kejì oṣu Kejila ọdun 2023, ọwọ ileeṣẹ Ọlọpaa tẹ Tijani Ahmadu Diye, ẹni ọdun marundinlogoji fun ẹsun pe o si wọ na iyawo rẹ, to si gbiyanju lati ṣekupa pẹlu ọmọ odo''

O tẹsiwaju ninu atẹjade naa pe "Bi ọrọ naa se de ọdọ wa, a gbera lọ si agbegbe naa, ti a si ti gbe iyawo, ẹni to farapa lọ si ile iwosan ni bi to ti n gba itọju.''

"Ọkunrin yi ke sita pe ole wọ ile rẹ, to si jẹ pe oun gaan ni ole to fẹ ja ninu ile ara rẹ.O kọlu iyawo rẹ pẹlu ọmọ odo ninu yara wọn.''

Alukoro ọlọpaa fikun pe "Iwadi ti bẹrẹ lori ẹsun ti wọn fi kan arakunrin naa.''

Bẹẹ lo ni awọn yoo gbe lọ si iwaju ile ẹjọ lati lọ wi tẹnu rẹ fadajọ.