You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Fífẹ́ ìyàwó Alaafin, àti ìgbà mẹ́rin mìí tí Portable da orí ayélujára rú
Odu ni gbajumọ olorin takasufe, Habeeb Okikiola, ti ọpọ tun mọ si Portable, ki i ṣe aimọ fun oloko lori ayelujara.
Ti wọn ba n sọrọ nipa gbajumọ olorin to tun lẹnu ni Naijiria, Portable gbọdọ jẹ ọkan lara irufẹ awọn olorin bẹẹ.
Ọpọ igba si ni ariwo ti sọ lori Portable, nitori iwa ati iṣe rẹ.
Lọjọ Isẹgun, ọjọ keji ọdun tuntun 2024 yii ni fidio kan kan jade sori ayelujara.
Ninu fidio naa ni Portable ti tu itọ soke to si foju gba a, pẹlu alaye pe ọkan lara awọn obinrin to bimọ fun un gbe ọmọ rẹ lọ sibi ayẹyẹ ayajọ Oshodi Day to waye nipinlẹ Eko.
Lati igba naa ni si ni ẹnu tun ti n kun Portable.
Wọn yi ni igba marun-un ti iroyin lorin Portable ti mi ori ayelujara titi:
Portable pariwo Koko Zaria ati "baby mama" rẹ lori ọmọ rẹ
Gbajugbaja olorin Zazu ke gbajare ninu fidio to fi lede lori ayelujara lori bi iya ọmọ rẹ, Honey Berry ṣe gbe ọmọ rẹ to pe ni ọmọ ọdun kan lọ si ibi ayẹyẹ Oshodi Day.
Portable fẹsun kan oṣere ati oniṣowo, Ganiyu Oyedepo ti ọpọ mọ si Koko Zaria pe o n ni ajọṣepọ pẹlu Berry to jẹ baby mama oun.
Koko ohun ti Portable n sọ ninu fidio to gbe jade ni pe Berry le tẹ le ọkunrin to ba wu u, amọ ki o ma gbe ọmọ oun lọ si pati tabi lọ ba ọkunrin kankan.
Portable kilọ fun Berry ati Koko Zaria ninu fidio to gbe jade pe k'awọn mejeeji da ọmọ oun pada laarin ọjọ meje, bi bẹẹ kọọ, gbẹgẹdẹ o gbina.
Olorin Zazu ni oun to gbanga sun lọyẹ, oun si ni ohun ti oun le fi kọ oju ija si Koko Zaria.
Portable àti Pasuma rọ òjò àlùjó lé àwọn olùjọ́sìn lórí nínú ìjọ Cele
Portable patẹ alujo ninu ile ijọsin Celestial Church of Christ, Land of Goshen Cathedral, to wa ni agbegbe Ogudu, nipinlẹ Eko, lasiko ti wọn n ṣe isin aṣalẹ iyin, ti awọn elede Gẹẹsi n pe ni Praise Night.
Laipe yii ni iroyin ti kọkọ gba ori ayelujara nipa bi ijọ awọn ọmọlẹyin Kristi ọhun ṣe fi iwe pe Portable to jẹ olorin ‘Aye’, ati akọrin mii, Pasuma to n naa jẹ akọrin Fuji.
Ọjọru, ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun 2023 ni iwe ipe to n kede Aṣalẹ iyin naa jade sori opo ayelujara Facebook.
Yatọ si Pasuma ati Portable ti wọn jẹ olorin aye, awọn eleto naa tun pe ọmọbinrin olorin kan torukọ rẹ n jẹ May-Shua.
Ikede naa fa ariyanjiyan, paapaa laarin awọn Kristiẹni to gbagbọ pe ko bojumu fun iru awọn akọrin bẹẹ lati kọrin ninu ile ijọsin.
Amọ, iyalẹnu lo jẹ nigba ti akọrin takasufe ọhun gunlẹ sibi eto isin naa ni alẹ ọjọ Ẹti, ọjọ karundinlogun, oṣu Kejila, to si kọrin lori itage.
Ninu fidio kan ti Ọgbẹni Portable fi si ori ayelujara Facebook rẹ, la ti ri i to n kọ lara awọn orin rẹ bi Zazoo, fun ẹgbẹẹgbẹrun eeyan to pejọ lati gbọ́, ti awọn naa si n kọrin tẹle e.
Yatọ si eyi, aṣọ funfun ti wọn n pe ni ‘Sutana’, eyi to jẹ aṣọ ti awọn ọmọ ijọ Cele ma n wọ, ni Portable wọ lati fi kọrin.
Portable fi ẹ̀ṣẹ́ fọ́ gbajúmọ̀ òṣèré sinimá, Charles Okocha lẹ́nu ní ìdíje ẹ̀ṣẹ́ kíkàn
Portable, ati oṣerekunrin, Charles Okocha, jọ fija pẹẹta ni ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2023, nigba ti wọn fi ẹṣẹ kikan wọya ija
Ija naa to waye ni eti okun Landmark, ni agbegbe Victoria Island nipinlẹ Eko, ni iroyin sọ pe o bẹrẹ ni nnkan bi aago kan oru.
Bi ogoji iṣẹju si ni wọn fi ja.
Iroyin sọ pe igba mẹrin ni wọn fi ẹ̀ṣẹ́ ja, ti ẹni kọọkan wọn si gbiyanju lati bori ẹnikeji.
Ni abala keji ninu ija naa, fidio kan to wa lori ayelujara ṣafihan bi Okocha ṣe fi ẹsẹ lu Portable ni alubolẹ. Ọpẹlọpẹ alamojuto ija naa to sare ko si wọn laarin.
Ni abala kẹta, awọn gbajumọ mejeeji gbiyanju lati bori, amọ nigba ti yoo fi di abala kẹrin, o jọ pe o ti rẹ awọn mejeeji. Ṣugbọn bo ṣe rẹ wọn to, ẹṣin kii kọ ere asarele ni Portable fi ṣe.
Awọn ẹsẹ to ko bo alatako rẹ ni wọn fi kede rẹ gẹgẹ bi olubori, bo tilẹ jẹ pe ko lo awọn ilana TKO tabi KO ti awọn akọṣẹmọṣẹ to n ja ẹṣẹ, ma n lo.
Ni ipari ija naa, Portable ni wọn gbe bẹliti olubori kọ ni ọrun.
A ko le e ṣọ boya ija wọn naa jẹ ojulowo, tabi ere idaraya fun awọn ololufẹ wọn.
Portable sọrọ lori ibasepọ rẹ pẹlu Olori Alaafin tẹlẹ, Damilola
Portable tu kẹkẹ ọrọ sita lori ibasepọ rẹ pẹlu Olori Alaafin tẹlẹ, Damilola.
Portable ṣalaye ọrọ lasiko to fi n kopa lori eto kan lori ayelujara.
O ni oun ko ba ti ni ohunkohun pẹlu iyawo Oba to ba jẹ pe Alaafin si wa laye ni.
O sọ ọrọ yii lasiko to n se ifọrọwerọ pẹlu Honest Bunch, to si jẹ ko di mimọ pe lẹyin Ọba, Ọba tun ni.
"Alatilẹyin mi lati ọjọ pipẹ ni, sugbọn nigba to ya, mo gbọ pe Ọba ti ku, lẹyin Ọba, Ọba tun ni.
"Ka ni Ọba si wa, ẹ ko ni ri emi ati rẹ papọ nitori n ko ki tẹle Iyawo oni iyawo kiri."
Portable tẹsiwaju pe oun ni ifẹ si gbogbo awọn iyawo oun pata, ti oun si nifẹ wọn dọgba papọ
"Obinrin to ba ti fun mi ni ifọkanbalẹ, mo ma ni ifẹ rẹ.
"Iyawo mi to wa ni ile, ko fun mi ni ifọkanbalẹ lasiko ti ilu mọ mi lo jẹ ki lọ fẹ obinrin pupọ.''
Portable foju ba ile ẹjọ lori ẹsun onikoko mẹfa
Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa, Muyiwa Adejobi fi oniruuru ọrọ sita loju opo Twitter rẹ lati ṣalaye iru ẹsun ti Portable yoo koju.
Adejobi jẹ ko di mimọ nigba to n fesi si eeyan kan lori Twitter to ni ileeṣẹ ọlọpaa kọ lati fi Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluomo jofin nigba to sọrọ to tabuku ẹya amọ wọn wa fẹ fi ofin gbe Portable bayii.
Adejobi ni “o da mi loju pe ẹ rii bi mo ṣe yanju ọrọ ti MC, amọ ni ti Portable, ẹsun to le ni mẹfa ni yoo jẹjọ le lori, yatọ fun pe ko jẹ ki wọn fi ofin gbe e ati pe o ṣe ọlọpaa kan leṣe.
Yoo foju ba ile ẹjọ lori ẹsun pe o lu ọkunrin kan ni agbegbe Otta ti ẹni naa si fi ẹsun kan an lọdọ Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ̀ Ogun.
Ọpọlọpọ ẹsun ni awọn eeyan tun ti fi kan an nipa ṣiṣe ikọlu si wọn torinaa, a o fi ọrọ wa a lẹnu wo.
Adejobi sọ pe ko si oju iṣaju labẹ ofin “torinaa ẹ jẹ ko foju ba ile ẹjọ ki a si gba awọn adajọ laye lati gbọ awọn ẹsun ti wọn fi kan an. Ko kọja ofin rara.”
Ẹwẹ, awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi aridaju han pe awọn fi panpẹ ofin mu Portable ti wọn si ni awọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti wọn fun un ni gbedeke oni wakati mejilelaadọrin lati bọwọ fun ipe ti ọlọpaa fi pe e.