Pope Francis, Bíṣọ́bù àgbà ìjọ Canterbury bẹ̀rẹ̀ àbẹ̀wò mánigbàgbé fún àlááfíà lórílẹ̀èdè South Sudan

Oríṣun àwòrán, Reuters
Poopu Francis to jẹ olori ijọ Katoliiki lagbaye, pẹlu olori ijọ Anglican, Biṣọọbu agba ijọ Canterbury pẹlu olori ijọ kristẹni kan lorilẹede Scotland ti gunlẹ si orilẹede South Sudan.
Igba akọkọ niyi ti awọn olori ijọ ẹsin kristẹni mejeeji yii yoo jọ rinrinajo pọ. Igbaradi fun irinajo wọnyi si ti bẹrẹ lati ọpọ ọdun sẹyin.
Ilu ati ijo ni wọn fi ki awọn olori ijọ mẹtẹẹta yii kaabọ ni papakọ ofurufu ilu Juba ki wọn to fi ọkọ gbe wọn laarin ilu ati ijo yii, ati ọpọlọpọ awọn ero ti rọ jade lati ki wọn kaabọ lẹba ọna gbogbo titi de ile aarẹ orilẹede naa.
Ninu ọrọ rẹ Justin Welby ti oun pẹlu Ẹniọwọ Iain Greenshields wa lara awọn to kọkọ fi oju kan Poopu Francis ati olori ijọ Anglican ti wọn si ki wọn kaabọ si orilẹede naa sọ pe, “Abẹwo manigbagbe ni eyi jẹ. Lẹyin iyapa ọpọlọpọ ọdun, gbogbo ẹka ijọ ti n pada parapọ lọna to yaayi.”
Eredi irinajo wọn ni lati mu ireti wa si orilẹede South Sudan ati lati ṣe koriya fun awọn adari orilẹede naa lati lọ eto alaafia ni alọye nibẹ.
“Adura wa ni pe ki abẹwo yii jẹ ọpakutẹlẹ fun awọn aṣiwaju orilẹede South Sudan lati gbajumọ awọn ohun ti yoo mu iṣọkan wa dipo awọn ohun ti yoo pin wọn niya nitori Oluwa fẹran wọn bakan naa ni.”
Eyi lọrọ Ẹniọwọ Greenshields ni tirẹ.
Pataki abẹwo rẹ lasiko yii

Oríṣun àwòrán, AFP
Abẹwo awọn eekan olori ijọ Kristẹni yii n waye lasiko ti orilẹede naa n koju rukerudo ọrọ oṣelu ti araalu nibẹ si n koju iṣẹ eyi to n mu ki ọ̀pọ onwoye o maa kọminu lori ọjọọla orilẹede ọhun.
Ogun abẹle ti bẹrẹ lorilẹede naa lati igba ti awọn adari rẹ ti fariga lori akoso rẹ lọdun 2013, lẹyin ọdun meji to gba ominira lọwọ Sudan.
Ko din ni ẹgbẹrun lọna ogoji eeyan, (40, 000) eeyan ti o ti ku nipasẹ dukuu yii. Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn adari igun oṣelu ni orilẹede South Sudan fọwọ si iwe adehun alaafia kan lọdun 2018, eyi to ṣokunfa idasilẹ ijọba ajumọṣe alaafia nibẹ, sibẹ ọ̀pọ awọn koko inu iwe adehun naa ni ko tii fidimulẹ.

Ida ọgọta ninu ọgọrun, (60%) ni wọn jẹ Kristẹni, ọ̀pọ wọn lo si jẹ ọmọ ijọ Katoliiki, Anglican ati Presbyterian. Amọ oju opo ẹya ni ogun to n waye nibẹ n gba, kii ṣe ti ẹsin.
Awon ololufẹ aarẹ Salva Kiir, to jẹ ọmọ ẹya Dinka, atawọn ololufẹ igbakeji aarẹ Riek Machar to jẹ ẹya Nuer lo n dana ogun lorilẹede South Sudan.
Lọdun 2019, Poopu Francis wole lẹsẹ awọn mejeeji yi lati fi ẹnu ko wọn li ẹsẹ gẹgẹ bi ara ipe rẹ fun idapada alaafia lorilẹede naa ati laarin awọn adadri igun oṣelu gbogbo nibẹ.












