Nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa abẹ́rẹ́ MenFive tí Naijiria fẹ́ fi má a kojú Meningitis

Oríṣun àwòrán, Getty
Ni bayii, orilẹ-ede Naijiria ni akọkọ ti abẹrẹ ajẹsara tuntun ‘MenFive’ to le dena aarun yirun-yirun (Meningitis) balẹ si.
Irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karun-un, oṣu Kẹta, ọdun 2024 ni abẹrẹ naa de si Naijiria.
Ajọ UNICEF to n ri si ọrọ awọn ọmọde lo gbe abẹrẹ naa wọ Naijiria, pẹlu ajọṣepọ ajọ Gavi.
Aarun yirun-yirun maa n saba ṣe awọn ọmọde, paapaa julọ lapa Ariwa Naijiria.
Ṣugbọn ni bayii ti abẹrẹ ajẹsara to le dena rẹ ti de, yoo kapaa kokoro ajakalẹ aarun naa ti wọn n pe ni ‘meningococcus C’.
Awọn ọmọde to to miliọnu kan ni afojusun wa lati fun ni abẹrẹ yii.
Ki gan-an ni abẹrẹ ajẹsara MenFive yii?
Marun-un ninu ipele aarun yii lo lagbara ju, awọn naa ni
A, C, W, Y ati X.
Abẹrẹ ajẹsara to le dena ikọlu rẹ lara eeyan, paapaa ti X, ni tuntun yii.
Gẹgẹ bi Dokita Tokunbọ Ọshin to jẹ ọga ni Gavi ṣe wi, o ni abẹrẹ MenFive yii le ṣẹgun yirun-yirun to n ja l’Afrika.
" Ọpẹlọpẹ abẹrẹ ajẹsara yii, a ti gbegidina ajakalẹ aarun yirun-yirun l’Afrika bayii.
’’Ni bayii, a ti ni irinṣẹ gidi to ṣee koju arun to n sọ eeyan di alaabọ ara to si tun n fa iku.
‘’Ileeṣẹ wa yoo maa sowọpọ pẹlu ijọba Naijiria ati ajọ eleto Ilera agbaye (WHO) pẹlu UNICEF lati koju ajakalẹ arun yii’’
Bi yirun-yirun ṣe n mu eeyan ati bo ṣe ri ni Naijiria lasiko yii
Arun aṣekupani to n daamu ọmọde ati agba ni yirun-yirun.
Alaye awọn dokita nipa rẹ ni pe o ni i ṣe pẹlu ọpọlọ ati ogooro ẹyin.
Awọn kokoro aifojuri bii Bacteria ati fungal naa maa n lọwọ si i nigba mii, gẹgẹ bi ajọ ilera agbaye, WHO, ṣe sọ.
Awọn apẹẹrẹ ti ẹni to ba ni aarun yii yoo maa ri ni ẹfọri, iba ati ki ọrun ma ṣe e yi.
Bi aarun yii ṣe le paayan naa lo le lọ funra rẹ, ohun to ba fa a ni yoo sọ itu ti yoo fini pa, boya iku ni abi iye.
Awọn itọju oogun apakokoro ta a mọ si ‘Antibiotics’ ni ẹni to ba mu nilo lati sare gba.
Laipẹ yii, nipinlẹ Yobe, eeyan igba le mẹfa, (206) ni wọn fi pamọ si agọ itọju nitori ajakalẹ aarun yirun-yirun to bẹ silẹ nijọba ibilẹ mẹta.
Ogun eeyan lo padanu ẹmi wọn ninu awọn eeyan naa.
Nipinlẹ Gombe, eeyan mẹfa di oloogbe nipasẹ aarun yii kan naa.














